Sanwó-Olú ṣèfilọ́lẹ̀ ilé ìkóúnjẹsí ní Mushin, ó tún ṣèlérí owó gọbọi fáwọn oníṣòwò
Ọlaide Gold
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ṣefilọlẹ owo idokowo ẹgbẹrun lọna igba mẹrin din laadọta naira fawọn ọlọja kaakiri ipinlẹ naa eyi to pe ni,owo iranwọ fawọn oni karakata nipinlẹ Eko iyẹn,Lagos Market Trader Money.
Sanwo-Olu kede iroyin naa lasiko to lọ ṣi ile ikounjẹsi kan lagbegbe Idi Oro, ni Mushin eyi to waye nipasẹ erongba rẹ lati jẹ ki ounjẹ wa lọpọ yanturu.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, owo tiye rẹ to ẹgbẹrun lọna aadọta naira lawọn olokoowo to le lẹgbẹrun mẹẹẹdogun yoo gba gẹgẹ bi owo iranwọ okowo latọdọ ijọba,eyi ti ko yọ awọn obinrin oniṣowo tiwọn wa ninu ọgba ṣọja ati ọlọpaa silẹ kiwọn le ṣe amulo rẹ lọna to tọ.
Ọkunrin akọkọ nipinẹ naa ni, ẹda ilẹ ikounjẹsi naa yoo wa nilu Agege, Ajah ati Abule Ado.
Nigba to sọrọ lori iṣẹ akanṣe naa, Kọmiṣanna fun eto ọgbin ati alajẹṣẹku,Arabinin Abisọla Olusanya, iwuri lo yẹ ki iṣẹ akanṣe naa jẹ fun araalu, o wa ṣeleri pe ounjẹ to dara lawọn yoo ma ṣe akojọ rẹ sinu ile ikounjẹsi naa.
Ẹwẹ, gomina Sanwo-Olu ti sọpe, ile ikounjẹsi to gbaaye daada yoo di kikọ sagbegbe Ketu-Ereyun nilu Ẹpẹ, eyi tiṣẹ yoo pari lori ẹ laipẹ ti wọn si ma ṣefilọlẹ ẹ lọdun to n bọ.
Comments
Post a Comment