Sanwó-Olú ṣayẹyẹ oúnjẹ fáwọn ọ̀dọ́ l'Ekoo


Ọlaide Gold

Bi pọpọṣinṣin ọdun keresimesi ṣe wa nita tawọn eeyan si n ṣaroye ko sowo atipe wọn n koju ọwọngogo ti ounjẹ ati epo bentiro da silẹ. Ironu onikaluku ṣọtọọtọ,bawọn kan ṣe n kọrin ko sowo lawọn kan n pariwo pe owo to wa lọwọ ko to ra nnkan kan.
Lọjọ Aiku Sannde to kọja ni gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu ṣe nnkan ara fawọn araalu nipa pipese anfaani lati ra ounjẹ lọpọ yanturu nibi ayẹyẹ ounjẹ to waye ninu ọgba ajara Muri-Okunọla  to wa ni erekuṣu Eko.
Oriṣiiriṣii ounjẹ ati ohun mimu lawọn ọlọja ko wa fun tita lọpọ yanuturu. Ṣe lawọn eeyan pe biba sibẹ koda ẹni ti ko le rin bẹbẹ pe ki wọn gbe oun lọ woran.
Awọn eekan alẹnulọrọ ninu oṣelu ni wọn kọwọrin pẹlu gomina wa sibi ayẹyẹ naa bẹẹ lọmọbinrin to se ounjẹ gbami ẹyẹ Guiness laipẹ yii,Hilda Bacci naa jẹ olukopa ninu ayẹyẹ ounjẹ naa.
Gomina Sanwo-Olu nigbati igbakeji ẹ,Dokita Ọbafẹmi Hamzat gbẹnu ẹ sọrọ nibi ayẹyẹ naa ni,nnkan to dara ni ki eeyan da si ọrọ ounjẹ ati gbogbo eto to le mu ki rira ati tita ounjẹ rọrun fun araalu nitoripe bi ounjẹ ba kuro ninu iṣẹ, a jẹ pe iṣẹ buṣe niyẹn. O tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe,awọn ọdọ gangan ni afojusun ijọba lati ṣeranwọ fun wọn latari awọn ounjẹ adidun tiwọn n ṣe nilani igbalode koda
Hamzat naa ṣe ounjẹ adidun nibẹ lọjọ naa       
Ọgọọrọ awọn eeyan ti wọn wa nibẹ lọjọ naa ni wọn gboṣuba kare fun gomina naa fun igbesẹ ẹlẹyinju aanu to gbe,ọkunrin kan to pe orukọ ara ẹ ni,Ademọla Faṣakin ni oun ko tiẹ gbọ nipa eto naa tẹlẹ,o ni, lọjọ naa loun huu gbọ lọdọ ọrẹ oun kan toun si tẹle wa sibẹ ṣugbọn si iyalẹnu oun, nnkan to ṣẹlẹ nibẹ kọja nnkan tijọba gbọdọ bo mọlẹ. Ademọla ni ṣe loun ra ounjẹ lowo pẹntọ bẹẹ o yẹ kawọn eeyan pupọ jẹ anfaani iru nnkan bẹẹ.
Ọdọọdun ni wọn ni ayẹyẹ tita ati rira ounjẹ lowo pooku naa ma n waye ninu ọgba Muri-Okunọla ni erekuṣu Eko, nibẹ lawọn to ba fẹẹ ra eroja ounjẹ fọdun ti ma n pade bakan naa lawọn eeyan tun ma n lọ sibẹ fun igbafẹ latari ere ọlọkan-o-jọkan ti wọn ti pese silẹ lati da wọn laraya ati awọn ibudo itura lati mu ọti ẹlẹrindodo ati ẹmu ogidi.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.