ÒGÚLÙTU Ọ̀RỌ̀:Lánrewájú Adépọ̀jù: Àkànmú gbé ‘gbá ewì rèwàlẹ̀ àṣà


Ko si ololufẹ ede Yoruba ti ko ni i kọ haa ni ọsẹ to kọja nigba ti gbogbo aye gbọ pe agba ọjẹ akewi nni, Lanrewaju Adepọju, jẹ Ọlọrun nipe. Ṣe fun igba diẹ ni ọjọgbọn akewi yii ti ni ipenija oju  to si ke si awọn araalu ki wọn ran oun lọwọ, ṣugbọn ti ọrọ yiwọ nigbẹyin.

Ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin lai lero pe maa ni anfaani ti mo ni lonii lati jẹ olootu iwe iroyin  GBÉLÉGBỌ́, mo wa si ibugbe ọjọgbọn akewi yii niluu lbadan lati waa fi idunnu mi han si ogbontagiri akewi yii fun iṣẹ ribiribi to ṣe nipa ede Yoruba ati ibi ti ede naa n lọ. A sọrọ pupọ lori akori yii ti mo si kọ ọpọlọpọ ẹkọ ninu apero wa eyi to ṣi mi loju inu lati ri anfaani ati iyi to wa ninu ede abinibi.

Mo le fi ọwọ sọya lonii pe ọjọgbọn akewi yii jẹ gbongbo imọ ati orisun ifẹ ti mo ni si ede Yoruba titi di oni, nitori baba yii fi ewi rẹ sin mi ni gbẹrẹ ipakọ iwulo ede ati aṣa Yoruba.

A bi ọjọgbọn akewi yii ni abule kan ti wọn n pe ni Aba Oke Pupa ni nnkan bii ọdun mẹtalelọgọrin sẹyin, lasiko yii, bo ti ṣe nifẹẹ lati lọ sileewe to, ko ni anfaani yii, eyi lo fi pinnu lati maa kọ ara rẹ ni bi wọn ṣe n kọ ati ka ede Yoruba ati Gẹẹsi, eyi to sọ ọ di aayo laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

Nigba ti akewi yii wa ni ṣango ode, o ṣiṣẹ pẹlu ileewe iroyin nibi to ti kọ nipa ede oyinbo ati Yoruba daadaa. Lakooko yii lo gbe ọkan ninu awọn iwe to kọ ti akọle rẹ n jẹ ‘Ironu Akewi' jade. O gbiyanju lati ṣiṣẹ nileeṣẹ redio Iwọ-Oorun igba na, (WNBC/WNBS) nibi to ti maa n kewi lojoojumọ ti wọn pe ni abala ‘ijinji akewi’.

Ohun to daju ṣaka ni pe ewi kike eyi ti akewi yii ti ṣe yala ninu awo rẹkọọdu to gbe jade  ni tabi to kọ sinu iwe lo sọ ọ di gbajugbaja ilumọ-ọn-ka akewi, onkọrin ati opitan to muna doko, to gbounjẹ fẹgbẹ to si tun gbawo bọ.


Nigba to to akoko kan ti awọn ileeṣẹ redio fẹẹ jẹ gaba lori awọn iṣẹ to ti ṣe fun wọn ni Adepọju kọwe fiṣẹ silẹ to si da duro lati maa gbe rẹkọọdu ewi jade, eyi to sọ ọ di ilumọ-ọn-ka akewi to dantọ.

Gẹgẹ bi awọn ewi ikilọ to ma a n ke, eyi ti o fi maa n sin ijọba ni gbẹrẹ ipakọ, awọn ewi bii, Nibo la n lọ, Ilu le, Takute Ọlọrun, Igba oro ati bẹẹ bẹẹ lọ jẹ ohun to jẹ ki awọn ijọba, ni pataki julọ, awọn ijọba onikaki gbogun ti i, ti wọn si ti i mọle laimọye igba.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ọjọgbọn yii ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin, o fi ye mi pe lakooko ijọba ologun eyi ti Ibrahim Babangida jẹ aarẹ igba naa, oju oun ri mabo. "Ṣaaju akoko ti mo kọ ewi 'Iku Awolọwọ ni mo ti kọ lẹta si ijọba pe nibo ni wọn n wa ilu lọ ti gbogbo nnkan n polukurumuṣu. Mo fi lẹta naa ṣọwọ si Ọgagun Babangida lakooko naa, ṣugbọn mo reti titi ko si ẹni to da mi lohun.

" Nigba ti mo waa kọ ewi Iku Awolọwọ ti mo waa n ronu ohun ti mo fẹẹ kọ si abala oju keji ewi yii ni mo ranti lẹta ti mo kọ si aarẹ ologun. Ṣe ni mo tu lẹta ni ede Yoruba ni mo ba sọ ọ di orin ewi. Ni ọjọ ti ewi yii jade ni ijọba ranṣẹ waa mu mi ti wọn si bẹrẹ si ni i ko gbogbo awọn awo yii lori igba. Eyi jẹ ki awo yii jẹ itẹwọgba ti gbogbo awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan bẹrẹ si ni laali ijọba Babangida lori ọrọ yii."

Nigba ti oju ogun oṣelu le ti awọn kan sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan ni akewi yii wa, o fi ewi laali awọn elero kukuru yii pe ojisẹ Eledumare lakewi jẹ ati pe pẹtẹpẹtẹ ni ewi wọn, ẹni to ba ta si lara ni ko tun ibẹ ṣe. Asiko yii lo fewi sọ pe gbogbo awọn to n lepa oun, ọwọ ara wọn ni wọn yoo fi ṣe ara wọn.

Ẹni pe ki n ku, igi gbigbẹ ki i roju pewe, oku ọpẹ ki i yọmọ, abẹrẹ ajadi ki i roju ihunṣọ, kajere o roju gbomi duro irọ ni, ẹlalẹkẹ ki i roju bibọ lokun,  ki gbogbo aṣebi o maa fọwọ ara wọn ṣera wọn, eeyan to ba fẹẹ ṣemi nika, ko ṣera rẹ nika. Oodua, Ọlọfin, Baṣọrun Ajaka, Ajẹnjẹ Tiẹlẹ, ẹ ma jẹ kodo wọn o gbemi lọ, Oke Ibadan atage  ọlọmu oru ma sun. Ọranyan, Oluorogbo, Ṣango, ẹ jẹ kasa kòkó o ma a ba koko ẹ gbẹ, ti a ba ti rọju peri akọni, gaaraga la a fida lalẹ"

Ko si meji igi obi ninu igbo, o daju ṣaka pe arugbo ewi n bẹ lẹnu akewi yii, awọn ọrọ to wuwo bii apo ẹgusi, ẹbọra orin ti i bọni laṣọ, eṣu lẹyin gbogbo oṣika lawọn ewi rẹ. Bo tilẹ jẹ pe Adepọju kọ awọn iwe bii  Ironu Akewi, Ladepo Ọmọ Adanwo ati Sagba di were, Orin Ewi lo sọ ọ di gbajumọ ati ilu-mọ-ọn-ka akewi.

Diẹ ninu awọn ewi rẹ ni yii; Ilu le, Ọmọluabi, Ọmọ Oduduwa, Iku Awolọwọ, Ẹtọ ọmọniyan,Igba oro ki i fọ,Kadara, Oriki Eledumare, Alagbara, Ile ọba to jona, Ede aiyede,Takute Ọlọrun ati Ibi ori da ni si.

Ṣe Yoruba ti pari ọrọ nigba ti wọn sọ pe fifingba Ọlọra egbeje ni, aifingba Ọlọra ẹgbẹfa, bi Onirese ko ba fingba mọ, eyi to ti fin ko le e parun.

Larewájú ọkùnrin ṣàkà ṣíkí bíi ojú ẹ̀gún

Òkúta méjì baba èkùrọ́

Ọmọ ọ bọ́gún bọọ́gún

Ọmọ o bọ̀gùn bọọ̀gún

Ọmọ o bọ́ọgun bọ̀ọ̀gún

Ọmọ o bọọgun bọ̀gún

Àpáta pìtì tí jámọ láyà bí èpè ìkà

Mèsì ọ̀gọ̀ nílé olúyọ̀lé

Ẹ̀yin lọmọ ọ̀rọ̀ apata májà

Ẹ̀yin lọmọ sọbọ yọké

Ọmọ a ríké yan

Òjòlá a rómí wẹ̀

Nílé a rólú

Ìbàdàn mọ́jà mọjà

Tẹ́ fi kárá iwájú lẹ́rú

Bí ẹ bá meré wọn

Bí ẹ bá mọ àyínìke

Ẹ lè mo à yínì padà

Láì sara wọn

Láì sara wọn

Bẹ́ye bá fojú borò

Yó bà lọ ni.

 

 

 

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.