Emefiele wọ gàù!Wọ́n ní Buhari kọ́ ló fọwọ́ sí àtúnṣe owó Náírà*Làṣìírí àsùnwọ̀n bánkì rẹpẹtẹ tó ní nílẹ̀ òkèèrè bá tú



Ọmọlọla Oluwapẹlumi

Ko din ni asunwọn ẹgbẹta o din diẹ (593), ti ẹni to jẹ gomina tẹlẹ nileefowopamọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, ni kaakiri awọn ileefowopamọ ilẹ okeere bii Amẹrika, China, atawọn ibomi-in lai jẹ pe awọn igbimọ to n ri sọrọ ileefowopamọ ilẹ wa fọwọ si i. Koda, nibi ti wọn tanna wadii Emefiele de, ṣe ni aṣiiri tun tu pe aarẹ ilẹ wa ana, Muhammadu Buhari, kọ lo fọwọ si atunṣe owo Naira to ṣe, wọn ni aburo rẹ, Tunde Sabiu, lo sọ fun gomina tẹlẹ nileefowopamọ agba ọhun pe ko paarọ owo ilẹ wa.
    Oluwadii pataki ti ijọba apapọ bẹ lọwẹ lati tanna wadii Emefiele, Jim Obaze, lo tu awọn aṣiiri yii sita lọsẹ to kọja. O ni ṣe ni aṣiiri owo ilẹ okeere ti Emefiele ko pamọ silẹ okeere ti iye rẹ le ni ẹẹdẹgbẹta owo Yuro (£543, 482,213), tu soun lọwọ.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni Obaze gbe aabọ iwadii to ṣe kalẹ fun Aarẹ Bọla Tinubu. Odidi oṣu marun-un gbako ni oluwadii yii fi tanna wadii Emefiele, lasiko ọhun lo si jabọ pe ki i ṣe gomina tẹlẹ fun banki apapọ wa yii nikan lo lẹjọ ọ jẹ, o lawọn lọgaa-lọgaa nileefowopamọ agba yii naa ni alaye to pọ lati ṣe fun ijọba.
Ko din ni awọn lọgaa-lọgaa mẹrindinlogun ti Obazee fẹsun kan pe wọn lẹbọ lẹru, ti wọn si ṣe tiriliọnu lọna mẹrindinlọgbọn Naira ilẹ wa mọku-mọku.
    Bakan naa, ṣe ni igbimọ oluwadii yii tun fẹsun kan oluranlọwọ aarẹ tẹlẹ nilẹ wa, Tunde Sabiu, o ni oun naa lẹjọ ọ jẹ lori ọrọ yii. Gẹgẹ bi aabọ to jẹ, o ni Sabiu yii lo sọ ọrọ nipa atunṣe owo Naira fun Buhari atipe ṣe lo gun le igbesẹ naa lai jẹ pe igbimọ ileefowopamọ ilẹ wa fọwọ si i.
Iwadii Obaze fihan pe aarẹ tẹlẹ, iyẹn  Buhari, ko fọwọ si atunṣe owo Naira yii atipe Sabiu lo sọ fun Emefiele loṣu kẹsan-an, ọdun to kọja pe ko paarọ owo ilẹ wa. Ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja ni Emefiele fi lẹta kan ṣọwọ si Buhari pe oun ni in lọkan lati paarọ ọwọ Naira ilẹ wa. Wọn ni ki i ṣe pe Buhari fọwọ si atunṣe owo Naira yiu, ohun to kan sọ ni pe ilẹ Naijiria ni ki wọn ti ṣe gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe nipa rẹ.
Gẹgẹ bi Obaze ṣe jabọ, ṣe ni wọn ni Emefiele gbe iṣẹ atunṣe owo Naira yii fun ileeṣẹ ilẹ okeere kan, De La Rue, ni igba Pọun (£205, 000). Ṣe ni aṣiiri bi Emefiele ṣe tun ṣe owo iranwọ asiko Korona mọku-mọku tun tu sita.
Siwaju si, wọn ni biliọnu kan aabọ (1.7bn), ni gomina ana fun ileefowopamọ agba yii na lori awọn ẹjọ mọkandinlogun tawọn eeyan pe tako atunṣe owo Naira yii. Ṣe ni wọn tun ni awọn eeyan meji kan lo ayederu lẹta latọdọ aarẹ tẹlẹ, iyẹn Buhari, gba miliọnu mẹfa Dọla ($6.23mn), jade nileefowopamọ agba yii.
Ṣa, ọkan awọn lọgaa-lọgaa nileefowopamọ agba ilẹ wa yii ko balẹ mọ rara, wọn ni ẹru ti n ba wọn nitori wọn o mọ awọn orukọ ti Obazee da ninu abọ iwadii rẹ.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.