Àjálù nlá! Ọba alayé mẹ́ta wàjà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ógbomọ́ṣọ̀ọ́•Ibi ìnáwó òkú ni wọ́n n lọ


 

Kayọde Ọmọtọṣọ, Ibadan

Lọwọlọwọ bayii, inu ibanujẹ nla ni awọn araalu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ wa bayii lẹyin ti awọn kabiyesi mẹta lati ijọba ibilẹ Oriire, niluu Ogbomọṣọ,waja lasiko ti ọkọ wọn nijamba. GBÉLÉGBỌ́ gbọ pe adugbo Arinkinkin,niluu Ogbomọṣọ, ni ọkọ wọn ti nijamba lọjọ Ẹti, Furaidee,ọsẹ to kọja.

   Gẹgẹ bi akọroyin wa ṣe gbọ, ibi inawo oku iya ọbalaye kan, Oloolo ti Oolo, Ọba Oyebunmi Ajayi, ni awọn kabiyesi yii n lọ ko too di pe iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ. Awọn ọba to ba iṣẹlẹ ijamba yii rin ni Olodogbo ti Odogbo, Onibowula ti Bowula ati Alayetoro ti ilu Ayetoro. Akọroyin wa gbọ pe ibi ariya inawo yii ni wọn n lọ ko too di pe ọkọ wọn ko sẹnu tirela. Lẹsẹkẹsẹ ni Olodogbo jẹpe Ọlọrun,ti awọn meji to ku si dakẹ ko too di pe wọn gbe wọn de ileewosan.Ẹnikan to jẹ oṣiṣẹ nileewosan Ladoke Akintọla to wa niluu Ogbomọṣọ, fidi iroyin yii mulẹ fun akọroyin wa, pẹlu alaye pe wọn ti gbe oku awọn ọba naa pamọ si ile igboku si.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.