Afárá Ọ̀pẹ̀bí sí Ọjọ́ta yóò di àmúlò lọ́dún 2024-Sanwó-Olú
Ọlaide Gold
Lọjọ Iṣẹgun Tusidee ọsẹ to kọja ni gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu fidi ẹ mule pe afara Ọpẹbi si Mende wọnu Ọjọta yoo pari ti yoo si di amulo fawọn eeyan lọdun 2024.
Gomina Sanwo-Olu sọrọ yii lasiko to kọwọrin pẹlu awọn oniroyin lọ sibi iṣẹ akanṣe naa to n lọ lọwọ lagbegbe Odo-Iya Alaro, nibẹ lo ti fi da wọn loju pe, afara naa yoo faaye gba onimọto, onikẹkẹ ati ẹlẹsẹ ti wọn yoo si ma tẹle ofin irinna gẹgẹ bi wọn ti n ṣe lawọn ilu to laju.
Afojusun ijọba nipa afara naa ni lati mu adinku ba sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ eyi to ma n waye lojuna Allen si Ọpẹbi ṣugbọn ni kete tiṣẹ ba ti pari lori afara naa to si di amulo,irọrun lawọn awakọ yoo fi maa wọ awọn agbegbe bii, Ọjọta, Maryland, Ikẹja, atawọn agbegbe yooku.

Gẹgẹ bi alaye ti gomina ṣe fawọn akọroyin, iṣẹ akanṣe naa to bẹrẹ lọdun kan sẹyin ni yoo jẹ ọna ẹburu fawọn eeyan to fẹ lọ si Allen mọ Opebi bakan naa ni yoo ṣẹgun lilọ aimọye wakati ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ loju popo. O gboṣuba kare fun ileeṣẹ Julius Berger iyẹn kọngila to gbaṣẹ naa fun iṣẹ moriya ti wọn ṣe latari bi wọn ṣe yawọ siṣẹ naa ti wọn si tun ṣe ojulowo iṣẹ.
“Inu’ mi dun si iṣẹ iwuri tawọn kọngila taa gbeṣẹ fun ṣe muṣẹ naa ni pataki , afara naa yoo jẹ ara ọtọ eyi ti onimọto ati ẹlẹsẹ yoo ma ṣamulo rẹ tawọn onikẹkẹ paapaa yoo maa rin tiwọn lẹgbẹ kan laini idiwọ,iṣẹ akanṣe naa yoo pari lọdun 2024'.
Sanwo-Olu fasiko naa gba awọn to n ra ilẹ kaakiri ipinlẹ Eko nimọran pe, ki wọn maa ṣewadii ilẹ daadaa ki wọn to kowo lee , awọn ile kan wa tijọba maa wo lulẹ ki afara naa le kọja. Ọkunrin akọkọ nipinlẹ naa ni, ẹni to ba kanju kọle sipinlẹ Eko laiṣe iwadii ilẹ to fẹ kọle si le padanu ẹ lojiji bi ilẹ naa ba ti kọja alakalẹ ijọba.

Comments
Post a Comment