Afárá Ìkẹjà: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara gbóṣùbà káre fún Sanwó-Olú
Ẹṣẹ o gbero nilu Ikẹja l'Ekoo, Lonii gan ni gomina ipinlẹ naa, Babajide Sanwo-Olu ṣi afara mọto ti ojuna reluwe Redline Rail gba abẹ ẹ kọja nilu Ikẹja.
Afara mọto naa jẹ ọkan lara marun ti gomina naa kọ kaakiri agbegbe Eko, awọn eeyan si ti n foju sọna tipẹ,wọn ti n reti asiko ti biriiji mọto naa maa di amulo, ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo yoo dinku
ki gomina to bawọn ṣi i lonii, ọjọ kọkandinlogun oṣu kejila.
Ọga agba fajọ ileeṣẹ ijọba to n ri seto irinna l'Ekoo, iyẹn Lagos Metropolitan Area Transport Authority(LAMATA), Onimọ Ẹrọ,Abimbọla Akinajọ ninu ọrọ ẹ gboṣuba kare fun gomina ipinlẹ naa bi o ṣe n ṣiṣẹ iwuri lati ibẹrẹ iṣakoso rẹ, Obinrin naa ni, afara Ikẹja ni afara ẹlẹẹkẹrin ti Sanwo-Olu ti kọ lati mu ki lilọ bibọ ọkọ rọju.Akọọkọ ni ti Agege,ikeji ni ti Yaba nigbati afara Oyingbo ṣekẹta, afara Mushin naa yoo di amulo laipẹ bẹẹ gbogbo awọn afara naa niwọn fo ori ojuna reluwe kọja iyẹn ọkọ Redline Rail ti lilọ bibọ wọn ko si nii di ara wọn lọwọ.
Gomina Sanwo-Olu nigba to ṣalaye nipa iṣẹ akanṣe naa lo ti jẹ ko di mimọ pe, ilana ti gọmina ipinlẹ Eko tẹlẹ ẹni to ti di aarẹ orileede bayii,Aṣiwaju Bọla Tinubu fi lelẹ loun n tẹle atipe ijọba apapọ ti ṣeleri lati kun ipinlẹ Eko lọwọ nipa pipese ọkọ boginni bii ọgọrun lati koju iṣoro irinna.
"Afojusun wa nipe, reluwe 'Redline' a maa ko ẹẹdẹgbẹta ero lojumọ,ni irinajo kilomita mẹtadinlọgbọn lati Agbado si Oyingbo,awọn idikọ to ti maa duro ni Agbado,Iju,Agege,Ikẹja,Oṣodi,Mushin,Yaba titi to fi ma pada si ebute rẹ ni Oyingbo, a fẹ mu da yin loju pe awọn eeyan ipinlẹ Eko o ni koju iṣoro irinna mọ."
Gomina ipinlẹ Kwara,Mallam AbdulRahman AbdulRasak naa ko ṣai kan saara si Sanwo-Olu fun aṣeyọri iṣẹ akanṣe ara ọtọ naa, o ni,Ipinlẹ Eko ti n jẹ anfaani awọn gomina onitẹsiwaju latigba iṣakoso Aṣiwaju Bọla Tinubu lasiko to jẹ gomina ipinlẹ naa bẹẹ idaniloju wa pe Tinubu yoo sọ Orileede Naijiria naa di awokọṣe.
Alaga ijọba ibilẹ Ikẹja,Ọnarebu Mojeed Balogun dupẹ lọwọ gomina atawọn adari
ẹgbẹ APC, O ni bi o tilẹ jẹpe awọn eeyan agbegbe Ikẹja ti n reti nnkan ara ọtọ bẹẹ tipẹ ṣugbọn itan ko nii gbagbe pe lasiko iṣejọba Sanwo-Olu lo waye. Balogun ṣeleri fun gomina pe ijọba ibilẹ naa yoo ri dajupe awọn ọmọ ganfe o nii ba afara naa jẹ.
Awọn eeyan pataki ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni, abẹnugan ileegbimọ aṣofin Eko, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, aṣoju Ọba ilu Eko, Oloye Agba Lateef Ajọsẹ, Iyawo gomina ipinlẹ Eko, Dokita Ibijọkẹ Sanwo-Olu, iyawo igbakeji gomina, abilekọYA WO Olurẹmi Hamzat, alaga ẹgbẹ APC l'Eko, Oloye Conelius Ọjẹlabi, Oloye Tajudeen Oluṣi,Oloye Mutiu Arẹ, awọn akọwe agba nileeṣẹ ijọba, iyawo awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn alẹnulọrọ lawujọ.
Comments
Post a Comment