Òògùn olóró láàrin àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama l’Ékòó: Èṣù ti gbà'jọba


Ṣe Yoruba bọ wọn ni oju a-pẹ-lode maa n ri, bẹẹ ni ti eeyan ba pẹ to ti n dẹ isa, ko ni i pẹ ti yoo fi pade abuke okete. Itumọ aṣamọ yii ni pe o jẹ ohun iyalẹnu fun mi laipẹ yii gẹgẹ bi oniroyin lati gbagbọ pe oogun oloro gbilẹ laarin awọn ọmọ ileewe girama nipinlẹ Eko, eyi to jẹ ki ominu maa kọni.

Yoruba ni ọrọ lo ba mo ko mo ro wa,  ti aja ba n gbo aja ya ri nnkan ni, ọmọ odo ko si gbọdọ na iya rẹ lasan. Iriri ti mo ri lọsẹ to kọja yii ya mi lẹnu o si tun jọ mi loju bi oogun oloro ṣe gbilẹ laarin awọn ọmọ ileewe girama kekere(JSS).

Ni ileewe kan ti mo forukọ bo laṣiiri ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ. Ọkan ninu awọn ọmọ to wa ni kilaasi ipele keji ni ileewe kekere yii ni agbegbe Festac Town, lo sọ fun ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa ni kilaasi kan naa pe o da bii pe ori n fọ oun. Ni wara-n-se-sa ni o tọwọ bọ apo to fun ọrẹ rẹ ni oogun kan pe ko lo ati pe to ba ti lo o tan, ori fifọ rẹ yoo walẹ.

Lai-deena-pẹnu, wakati mẹrinlelogun ni ọmọ yii fi sun eyi to ko awọn obi rẹ siyọnu. Nigba ti wọn de ileewosan ni aṣiiri ohun to ṣẹlẹ too ye wọn. Lẹyin ti ọmọ yii ji ni wọn beere ohun to ṣẹlẹ. Lai mọ iru oogun to lo, nigba ti wọn yẹ apo ifalọwọ ti ọrẹ rẹ ti mu oogun jade ni wọn ba ogún(20) oogun oloro ti wọn n pe ni tramadol, oniwọn igba(200m).

Ori lo ko ọmọde yii ti ọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹtala lọ, to jẹ pe ẹyọ kan oogun yii ni wọn fun un lo. Bo tilẹ jẹ pe awọn ajọ to n ri si didẹkun gbigbe ati lilo oogun oloro (NDLEA), ti da si ọrọ yii, ṣugbọn ọrọ naa bi Ige, bẹẹ lo bi Adubi. Ṣe lo da bii pe ọga ileewe yii n la ala nigba to ri ohun to ṣẹlẹ ni ileewe rẹ ati bi oogun oloro ṣe waa di meji eepini laarin awọn ọmọ majesin yii.

Eyi to tun da bii rẹ to n kọni lominu ni ti iṣẹlẹ kan to waye nipinlẹ Eko laipẹ yii nigba ti obinrin kan lọ si ile-itaja nla kan ti a fi orukọ bo laṣiiri lati lọọ ra ohun adidun inu ọra(lolly pulp) ti awọn ọmọde maa n fẹran lati mu pẹlu erongba lati fun awọn ọmọ keekeeke nileejọsin rẹ lọjọ isinmi.

Si iyalẹnu awọn ara ṣọọṣi yii, ni nnkan bii wakati kan ti awọn ọmọ wọnyi mu  'lolly pulp' yii tan, ṣe ni wọn n ṣe wérewère, ti diẹ ninu wọn si sun oorun ọpọlọpọ wakati. Eyi lo jẹ ki alufaa ijọ yii fura ti wọn si  ko iyooku 'lolly pulp' yii lọ fun ayẹwo nibi ti wọn ti fi ye wọn pe oogun oloro 'tramadol' wa ninu ohun adidun inu ọra yii.

Ohun ti awọn akiyesi yii n tọka si ni pe esuke ti wọ rara ati pe eṣu ti gba ijọba laarin awọn majesin yii ayafi ki awọn obi ati ijọba tete wa wọrọkọ fi ṣada lati dẹkun iwa ibajẹ yii.

Ninu itọpinpin ti GBÉLÉGBỌ́ ṣe lati ri i pe ọrọ yii ti kọja ohun ti a le fi yọbọkẹ mu.Ni awọn ileewe girama to wa ni agbegbe Agege, oogun oloro "Tramadol" ti di meji eepinni laarin awọn ọmọ ileewe yii, eyi to buru ju ni pe ṣe ni wọn maa n ko oogun yii sinu baagi wọn, ti wọn yoo si maa ta a fun awọn akẹgbẹ wọn to ba fẹ.

Ọkan ninu awọn tiṣa ileewe yii to ba wa sọrọ sọ pe ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun laipẹ yii nigba ti oun yẹ baagi awọn ọmọ kilaasi akọkọ onipele kẹta (JSS3) bii meji kan wo ti oun si ba pali "Tramadol" ati rọba idaabobo.

O sọ pe ileewe yii ranṣẹ si obi awọn ọmọ naa lati tọpasẹ ibi ti wọn ti ri awọn nnkan wọnyi, ṣugbọn awọn obi wọn ko ri alaye kankan ṣe nitori inu okunkun ni awọn naa wa ati pe baba ọkan ninu wọn bu sẹkun pe iya ọmọ yii ni ko moju to o nitori ẹẹkan lọsẹ loun maa n yọju sile nitori iṣẹ aje ti sọ ọmọ oun nu bii oko.

Iwadii ti GBÉLÉGBỌ́ ṣe fihan gbangban pe ṣe ni awọn ọbayejẹ ọmọ-pọ-bii- ọsan to kun awọn adugbo lakooko yii n lo awọn ọmọ ileewe yii lati ta awọn oogun oloro wọn, eyi ti ọpọlọpọ obi ti ko ni akiyesi ko le mọ.

Laipẹ yii ni ajọ kan ti ki i ṣe tijọba ti wọn n pe ni “lnternational leadership programme” ṣeto ilanilọyẹ nipa oogun oloro laarin awọn ọmọ ileewe fun awọn akẹkọọ kan niluu Eko.

Erongba ajọ yii ni lati ta awọn ọdọ yii ji nipa aburu ti oogun oloro le fa si igbesi aye wọn ati ọpọlọpọ ewu to rọ mọ lilo oogun oloro. Ajọ yii to gbe ipolongo wọn lọ si ileewe ijọba to wa ni Ọkọta  ati ljẹshatẹdo sọ pe awọn gbe igbesẹ yii lati le gba ọjọ iwaju awọn ọmọ ileewe yii kuro lọwọ iwa ipanle, fifipa banilopọ ati iwa jagidijagan ti aṣilo oogun oloro yii le fa si aye wọn.

 Aarẹ ẹgbẹ yii, Abilekọ Adetohun Tade, sọ pe ko si wa-ka-tẹ-tufọ-aja kankan ninu ọrọ to wa nilẹ yii nitori awọn kan lo sọ awọn ọmọ ileewe yii kan di agbode gba fun tita oogun oloro fun awọn akẹgbẹ wọn.

Arabinrin yii sọ pe o ya oun lẹnu lati ri i pe awọn ọmọ wọnyi mọ ọpọlọpọ ohun ti agbalagba ko mọ nipa oogun oloro  nitori pe ni adugbo ti wọn n gbe ni wọn ti kọ wọn ni iṣẹ buruku yii.

Aaya ti bẹ silẹ, o bẹ sare bẹẹ ni ọfọn-ọn-ọn ti tọ si gbẹgiri, ki onikaluku ko ẹkọ rẹ dani lori ọrọ oogun oloro yii ni. Asiko ti to ki ijọba gbe igbesẹ to nipọn lori ọrọ yii, nitori ti a ko ba tete pa ẹkan iroko ni kekere, to ba dagba tan, ẹbọ ni yoo maa beere. Bẹẹ si ni Yoruba sọ pe ti a ko ba tete gbe ọbọ wọgbẹ, ọbọ le gbeni wọgbẹ.

 

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.