Olùkọ́ tó ń fipá báwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sùn lóun fi wọ́n pàrònú rẹ́ ni



Johnson Akinpẹlu

Ọrọ buruku toun tẹrin, lọrọ Arakunrin kan, Ọlaniran Lateef Adewale, to jẹ olukọni nileewe giga Ebenezer Grammar School, Ibẹrẹkodo,  niluu Abẹokuta, ti wọn mu lori ẹsun pe o n fipa bawọn akẹkọọ ẹ sun, nigba to sọ pe oun fi wọn pa ironu rẹ ni.
 Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iṣẹ iṣiro ni wọn sọ pe tiṣa naa n kọ awọn ọmọleewe, to si n n ṣiṣẹ labẹ ijọba ipinlẹ Ogun, pẹlu nọmba ẹ to jẹ OGNO.30650, ọmọ ijọba ibilẹ Ipokia ni wọn pe e pẹlu.
Ninu ọrọ Ọnarebu Motunrayọ Adijat Adelẹyẹ, to jẹ kọmiṣṣanna fọrọ awọn obinrin, lori iṣẹlẹ naa, o sọ pe lara awọn ọmọ ikọ ẹ ni ọkan lara awọn ti tiṣa naa maa n ko ibasun fun pe, tawọn si bẹrẹ igbesẹ loju ẹsẹ.
O ṣalaye pe,,’’ Lọjọ Abamẹta, Satide, ni ọmọleewe binrin kan pe ikọ lara awọn eeyan mi pe ọkunrin kan fi tipa ba oun sun. Loju ẹsẹ ni a si ti gbe igbesẹ lori ọrọ to sọ nipa ṣiṣe ayẹwo fun un ko to di aa mu lọ si teṣan awọn ọlọpaa lati gba ọrọ ẹnu ẹ silẹ’’ Kọmiṣanna tun fikun ọrọ ẹ pe awọn lọọ sile ọkunrin afurasi naa pẹlu awọn ọlọpaa, tawọn si kan ilẹkun ẹ titi ṣugbọn ti ko ṣi fawọn. Eyi lo jẹ kawọn wa ẹgbọn ẹni to nile ọhun, to jẹ kawọn raye wọnu ile ọhun.
  Adelẹyẹ tun sọ pe,’’ Awọn gbọ ohun ọmọleewe mi-in nigba tawọn wọnu ọgba ileewe naa nibi to ti n pariwo pe kawọn ara adugbo gba oun, tiṣa yii tun fi tipa ba oun naa sun lakooko naa ni.
Ṣe lọmọbinrin naa sọ pe ṣe ni Ọlaniran fipa ba oun sun, to si tun halẹ mọ oun yoo pa oun tawọn obi oun ko ba fowo ranṣẹ si oun. Ni bayii, wọn ti fi  tiṣa naa si atimọle ni Eleweran, l’ Abẹokuta, nibi ti iwadii si tun ti tẹsiwaju.


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.