Èfún-àbéèdì:Wòlíì fi kùmọ̀ fọ́ ọmọọmọ rẹ̀ lórí, ó ló lẹ òkò mọ́ òun
Kayọde Ọmọtọṣọ,Ibadan
Laduugbo Papa Ẹlẹyẹ,Zone 2, nijọba ibilẹ Oluyọle, niluu Ibadan, ni ọkunrin kan,Wolii Gbenga Idowu Ogundijọ, ti lu ọmọọmọ rẹ, Keji Ogundijọ, pa.Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide,ọsẹ to kọja niṣẹlẹ yii ṣẹlẹ.Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe ṣalaye fun GBÉLÉGBỌ́, ariwo ni awọn ara adugbo yii gbọ ti wọn fi sare de ẹnu ọna yara Wolii Ogundijọ, nigba ti wọn si debẹ, titipa ni wọn ba ilẹkun naa, ṣugbọn awọn eeyan ja a wọle ti wọn si ba ọmọ ọhun nipo to lagbara.
Ṣe ni wọn de ọmọ ọhun lapa, ẹsẹ ati ọrun,ti gbogbo ori rẹ si ti fọ.Inu agbara ẹjẹ lo wa ti awọn eeyan fi sare gbe ọmọ ọhun digbadigba lọ sileewosan aladaani kan nibi to ti wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Nigba ti wọn de ileewosan, wọn ṣakiyesi pe wọn so ọmọ ọhun lokun lọrun
Ṣugbọn ṣa, ṣe lawọn ikọ Oluyọle Security Network, ti Oluṣẹgun Idowu jẹ ọga fun ṣawari wolii ọhun to pe orukọ rẹ ni Idowu Ogundijọ.Ṣe lo ṣalaye pe "loootọ, mo de ọmọọmọ mi lokun nitori pe o n jale.Ki i ṣe pe mo fẹẹ pa a, mo kan fẹẹ kọ ọ lẹkọọ pe iwa ole jija ko daa ni."
Baba to bi ọmọ naa, Gbenga Idowu Ogundijọ, ṣalaye pe "ẹni ọdun mejilelọgọrin ni mi.Ọmọ bibi ilu Ibadan ni mi, agboole Adegbayi, nita baalẹ si nile wa. Emi ni ẹkẹfa baalẹ ti Adegbayi Ọdun 2015 ni mo fẹyinti nidii iṣẹ ijọba."
Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ, o ni "ọmọọmọ mi to wa lọdọ mi, Keji Ogundijọ, ọmọ ọdun mọkanla,lo jẹ pe o ti n huwa ti ko daa lati ọjọ to ti pẹ ti ko yiwa pada. Ole lo maa n ja, ko sẹni ti ko mọ pe o n jale.Mo sọ fun un pe ko yẹ ko maa lọọ mu nnkan eeyan laduugbo.Lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, ṣe lo waa beere owo ounjẹ aarọ lọwọ mi laago meje aarọ, mo si sọ fun un pe ilẹ o ti i mọ.
"Mo fi sidii iṣẹ wẹda pe ko maa lọọ kọ, ko da mi lohun.Aarọ ọjọ naa to waa beere ounjẹ ti mi o fun un lo ba bọ sita to si bẹrẹ si i ṣepe fun mi. Bi mo ṣe bọ sita niyẹn ti mo bi i pe ki lohun to ṣẹlẹ to fi n ṣepe fun mi lai jẹ pe mo ṣẹ ọ? Mo ni mi o fẹẹ ko o hu iru iwa buruku ti baba rẹ hu to fi sọ di ohun to da lonii ni. Ọmọ yii o mọ iya rẹ ati baba rẹ rara, emi ni mo n tọju oun pẹlu ekeji rẹ lati kekere.Bi mo ṣe wọle pada bayii lo mu oko nilẹ to bẹrẹ si i ju u mọ mi. Ekeji rẹ n bi i pe kilo de to n le oko mọ baba, ṣugbọn ko da a lohun.O tun mu oko o ju mọ paanu mi.
"Mo tun wọ inu baluwẹ pe ki n wẹ lo tun bẹrẹ si i lẹ oko mọ mi.Bi mo ṣe wẹ tan bayii ti mo n mura lo tun mu oko, lo tun n lẹ mọ mi.Bi mo ṣe mu un niyẹn ti mo n lu u.Mo lu u lori, mo na an lẹyin pẹlu kumọ.Adura ti mo n gba ni pe ki ọmọọmọ yii ma ku, mi o fẹ ko ku rara."
Lọwọlọwọ bayii, ileewosan Ọna Iye, ni Omiyale ni wọn gbe ọmọ yii lọ nibi to ti n gbatọju lọwọlọwọ.
Comments
Post a Comment