Atiku: Ojú ti elégédé, ọbẹ̀ kan nínú àwo
- Get link
- X
- Other Apps
Yoruba bọ wọn ni ka da a lẹ ka tun un ṣa, ki i ṣe bii ti onigaari. Laipẹ yii ni ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ yii dajọ pe gbogbo awuyewuye awọn alatako nipa idibo aarẹ to kọja ko fi ẹsẹ mulẹ ati pe ariwo lasan ni aroye wọn ja si ninu ọrọ ofin.
Bo tilẹ jẹ pe abajade ile-ẹjọ yii ko tẹ oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar lọrun, ko si ohun to le ṣe lori eleyii, aṣọ ko ba ọmọyẹ rẹ mọ, ọmọyẹ ti rinhoho wọja.
Eleyii lo jẹ ko pe ajọ oniroyin lati fi ẹdun ọkan rẹ han eyi ti awọn lameetọ ninu oṣelu ti bẹrẹ si ni yiri rẹ wo bii agbado ori ina. Ohun to daju ṣaka ni pe o ṣoro fun awọn oloṣelu Naijiria lati fara mọ otitọ nipa ọna ofin, ni pataki julọ ti ko ba ti jẹ ohun to wa ni iha tiwọn.
Gbogbo awọn ọjọgbọn ninu imọ ofin to ri ibi ti ẹjọ yii fori gunlẹ si lo kan saara fun iṣẹ ọpọlọ ati titu yẹbẹ ofin ti igbimọ to ri si ọrọ oṣelu to kọkọ da ẹjọ yii gbe kalẹ ko too di pe Atiku tun tẹsiwaju lati gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ to ga julọ lorieede yii.
Ko si ohun to buru rara fun Turaki Adamawa lati gbe igbesẹ yii gẹgẹbi ọmọ Naijiria ati pe o lẹtọọ si i labẹ ofin lati ṣe bẹẹ, ṣugbọn ohun to buru jai ni pe nitori ti abajade ile-ẹjọ naa ko gbe si i lẹyin, a jẹ pe ki i ṣe idajọ ododo. Fun ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ fun ọdun mẹjọ, erongba yii ku diẹ ka-a-to, bẹẹ ni ohun to n tọka si ni pe iku nikan ni ẹbun to maa n tẹ ọmọ eniyan lọrun.
Ninu ipade oniroyin ti Atiku pe lo ti bu ẹnu atẹ lu idajọ ile-ẹjọ to ga julọ nilẹ yii pe ko kun oju oṣuwọn. O tun tẹ siwaju pe ṣe lo yẹ ki ile-ẹjọ yii kan ajọ to n ri si eto idibo nikoo fun iṣẹ ti ko kun oju oṣuwọn ti wọn ṣe nipa ọrọ idibo aarẹ to kọja.
Haaa, kilo de, nitori ipo yii abi nnkan miran? To ba jẹ pe Atiku mọ oore ti Ọlọrun ṣe fun un ni , ṣe lo yẹ ko gba kamu ko si maa dupẹ lọwọ ori rẹ awọn irinajo to ti rin ati awọn ipo ọla to ti gba kọja lai kawe kan lọ titi.
Ṣe ti ọmọde ba kọ iyan alẹ, o di dandan ki awọn agba fi itan balẹ, ni aarọ ọjọ wa nigba ti Atiku bẹrẹ irinajo rẹ gẹgẹbi aṣọbode, iwe-ẹri to fi wọle sibi iṣẹ yii jẹ ohun ti ko kun oju oṣuwọn rara, ṣe lo fọwọ juri lati ni kirẹdiiti meji pere ninu iwe-ẹri ti wọn fi gba a siṣẹ aṣọbode.
Ni akoko yii, awọn to ni kirẹdiiti mẹjọ ati awọn to ni ami mo-yege-tan ko ni anfaani lati wọ iṣẹ aṣọbode nitori wọn ko ni baba nigbẹjọ. Yatọ si eleyii, Atiku si gba igbega titi to fi di ọga lẹnu iṣẹ yii, lai ni iwe-ẹri miiran ko too di pe o fi iṣẹ naa silẹ.
Iru ẹni ti Ọlọrun ran lọwọ fun anfaani to ga ju yii, to tun waa mu depo igbakeji aarẹ fun ọdun mẹjọ yẹ ko kun fun ọpẹ ati idunnu ibi ti ori gbe e de, ki i ṣe pe ko waa maa lu ilu ọtẹ nitori ti ipo aarẹ ko ja mọ ọn lọwọ.
Tootọ ni ọja oṣelu lagbara, bẹẹ ni o kun fun iwa eeri gbogbo pẹlu tẹmbẹlẹkun ati arankan, ṣugbọn ti eeyan ba n gbẹ koto fun ọta rẹ, ko yẹ ko gbẹ ẹ jin nitori omi le tẹyin wọgbin lẹnu ko si ja si iru koto bẹẹ, eyi lo ṣẹlẹ si Atiku ọmọ Abubakar
Ṣe ara meririiri ni bi Atiku ṣe kọ ninu itan igbesi aye rẹ bo ṣe lọ si ileewe lai mọ pe awọn kan to mọ fin-in idi kókò yoo ṣe ọrinkiniwin ohun to kọ ninu iwe naa. Ṣe lo da bii aala lati gbọ pe Atiku sọ pe oun gba iwe imọ ijinlẹ ẹlẹẹkeji lai gba iwe imọ ti akọkọ. Oun nikan ni atori podi iru ẹkọ bayii ye, nitori ko siru eyi lawujọ awọn ọlaju.
O ma ṣe o, o bọ lọwọ ọmọ to n jẹ eeru. Ikan ko gbekan ọmọ Bantalẹ, ikan n jẹ eeru, ikeji n jẹ iyẹpẹ. Atiku ti ki ba fi ẹsin rẹ pamọ ko gba kamu pe Ọlọrun nikan ni gbeni depo, o fẹẹ fi wọdu-wọdu jale agbọn lai mọ pe itakuta ni agbọn n ta ni.
Ninu iwe rẹ to kọ nipa bo ṣe lo igbesi aye rẹ, aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti Atiku ṣe igbakeji rẹ sọ pe “mi ko ti i ri opurọ to to Atiku laye yii ri. Orukọ Atiku wa ninu orukọ ti awọn ilu Amẹrika fi ranṣẹ pe awọn fẹẹ tọpinpin awọn iwa mọka-ruru ti wọn ti ṣe, nigba ti mo ri gbogbo aṣemaṣe yii, oju gba mi ti fun Atiku ati awọn to ko sodi”
Ti Ọbasanjọ, ti oun ati Atiku jọ lo saa ọdun mẹjọ gẹgẹ bii adari Naijiria ba le sọ eleyii nipa Atiku, aa jẹ wipe ẹni ṣubu ti pari ijo ati pe ti jẹjẹrẹ Atiku ba n jẹgi oro, igba wo ni keregbe Naijiria ko ni i di awati to ba pada di aarẹ.
Ṣe Yoruba gbọn pupọ ninu iran wọn nigba ti wọn sọ pe ko si bi ọrun agbanrere ṣe gun to, ko le ri ọjọ ọla. Iba ṣe pe Atiku mọ pe ofo lẹyin ọja ni gbogbo igbesẹ ibajẹ toun n gbe nipa Aarẹ Tinubu ni, ki ba ro o lẹẹmeji.
Ṣugbọn gẹgẹbi itan Ijapa ni ọrọ Atiku ri, wọn bi ọkọ Yanibo nibo lo ti n bọ ati nibo lo n lọ, Ijapa dahun o ni oun n tibi abuku bọ ati pe oun n lọ sode ẹtẹ, ati pe o digba ti oun ba tẹ ki oun too pada wale.
Atiku ti gbagbe pe ninu ọrọ mimọ oṣelu u ṣe, ọga l’okete Asiwaju ninu ẹranko to n ru ebu iṣu ninu oko oṣelu. Ti ẹgbẹrun aayan bii ti Atiku ba wọ kẹẹbẹ ija oṣelu lati lọọ pade agbebọ adiyẹ Ọmọ Olodo Idẹ, iko ẹnu lasan ni yoo fi sa a jẹ.
Yoruba bọ wọn ni ti ejo ba mura ijakadi, o yẹ ko mọ pe ti oun ba de agiyan awọn eerun, ẹtẹ ni yoo ba bọ, nitori wọn yoo fi ọrọ rẹ patan ni. O yẹ ẹni gbogbo ko ru oku ẹkun, ko yẹ aja Atiku.
Atiku ninu iwoye tirẹ, asiko ti to fun atunto ati atunṣe ajọ to n ri si eto idibo ati eto ofin, igba yii laarọ rẹ, nibo ni Atiku kọju si nigba ti o lo ọdun mẹjọ gẹgẹbi igbakeji aarẹ? Asiko ti to fun Turaki Adamawa lati jawọ ninu apọn ti ko yọ, ko da omi ila kana.c
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment