Lẹ́yìn irinwó ọdún táwọn òyínbó ti kó àwọn baba nlá wọn lẹ́rú lọ,Sanwó-Olú fẹ́ẹ́ kí àwọn ọmọ káàbọ̀ padà sílé
Orin ẹ pada wale ni gomina Ipinlẹ Eko,Babajide Sanwo-Olu n kọ bayii fawọn
ọmọ ipinlẹ naa to wa lẹyin odi, paapaa julọ awọn tiwọn ko lọ lasiko owo ẹru.
Ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Julius Marcus Garvey jnr, ọmọ bibi inu gbajumọ ajijagbara nni,Marcus Garvey lo lewaju eto naa ti wọn pe ni 'Ilẹkun Ipadabọ Ẹlẹẹkẹrin' iyẹn '4th Lagos Door of Return event.'
Adari ajọ to samojuto awọn ọmọ Nigeria lẹyin odi, iyẹn Nigerians in Diaspora Commission (NIDCOM), Ọnarebu Abikẹ Dabiri- Erewa lo kede eto yii ninu ipade to waye pẹlu awọn akọroyin lọjọ Aje, Mọnde lọfiisi ijọba to wa nilu Alausa l'Ekoo,nibẹ lo ti fidi ẹ mulẹ pe, ijọba ipinlẹ Eko lọwọ seto naa.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ ,’’ Ṣiṣi ilẹkun ipadabọ naa silẹ ni lati gba awọn ọmọ iya wa pada sile ati lati ki wọn kaabọ sorilẹ ede baba nla wọn. O ni , o ti le nirinwo ọdun tawọn oyinbo amunisin ti ko awọn baba nla wa lẹru lọ koda iran karun ẹlomin lo ṣi wa lẹyin odi titi dasiko yii ṣugbọn ijọba ti ṣetan lati ki wọn kaabọ gẹgẹ bi ọba.
Ọjọ kọkanlelogun oṣu yii ni ilẹkun ipadabọ naa yoo fidi irinajo afẹ mulẹ siwaju sii nilu Badagry toripe gomina Babajide Sanwo-Olu lo ma gbawọn alejo wọle lọjọ naa bakan naa ni Dokita Julius Marcus Garvey jnr. naa yoo wa nikalẹ gẹgẹ bi alejo pataki.
Afojusun ijọba ni lati sọ ilẹkun ipadabọ naa di ibudo irinajo afẹ to ma lokiki kaakiri agbaye.
Comments
Post a Comment