Iléeṣẹ́ mọ́tò GAC ṣàfihàn ọkọ̀ ẹgbẹ̀rún méjì nípínlẹ̀ Èkó
- Get link
- X
- Other Apps
Gomina Babajide Sanwo-Olu ko le pa idunnu rẹ mọra nigbati wọn mu kaakiri ọgba ileeṣẹ naa to si ri ohun ara awoyanu to n lọ nibẹ.
Sanwo-Olu gboṣuba kare fawọn alaṣẹ ileeṣẹ naa, O ni, ireti nla nigbesẹ naa jẹ toripe yoo pese iṣẹ rẹpẹtẹ fun awon eeyan ipinlẹ Eko ati Orileede Naijiria lapapọ. Ọkunrin akọkọ nipinlẹ naa ni, ileeṣẹ ti wọn ti to ọkọ ẹgbẹrun meji jọ naa yoo tunbọ mu ki ajọṣepọ to dan mọran wa laarin awọn ileeṣẹ ile okeere ati Orileede Naijiria.
Ninu ọrọ Diana Chen, iyẹn alaga ileeṣẹ naa, O ni, lọdun 2020 ni pọpọṣinṣin idasilẹ ileeṣẹ naa bẹrẹ lasiko isede atankalẹ arun Korona, o ni, asiko naa ni ibaṣepọ waye laarin ileeṣẹ naa pẹlu ijọba ipinlẹ Eko, nigba naa ni wọn tọwọ bọ iwe adehun lati da ileeṣẹ naa silẹ.
- Get link
- X
- Other Apps
Comments
Post a Comment