Sanwó-Olú kọ iléèwé ìgbàlódé sílùú Ọ̀gọ̀mbọ̀


Ọlaide Gold
Gomina Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni, Babajide Sanwo-Olu ṣiṣọ loju ileewe girama Ọgọmbọ Community Secondary School. ileewe tuntun naa tawọn iyawo awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn pe ni Committee of Wives of Lagos State Officials (COWLSO) labẹ akoso Dọkita Ibijọkẹ Sanwo-Olu kọ fawọn akẹkọọ agbegbe Eti Ọsa l'Ekoo ni yaara ikẹkọọ mẹẹẹdogun, yaara alaarẹ iyẹn Sick Bay,yaara ikawe igbalode,Library ati aaye gbalasa fun ere idaraya. Ninu ọrọ ẹ nibi ayẹyẹ naa,Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu, ni ileewe naa waye latari adehun ti gomina Sanwo-Olu ṣe fun ilu Ọgọmbọ lasiko ipolongo ibo atipe ika eniyan lo ma ṣe adehun ti ko mu ṣẹ.
obinrin akọọkọ nipinlẹ naa wa gbawọn akẹkọọ naa nimọran pe ki wọn lo yaara ikawe naa daadaa bakan naa lo rọ awọn ara agbegbé naa ki wọn maṣe gba fawọn to ma n ba dukia ijọba jẹ lasiko ifẹhonuhan lati fọwọ ibajẹ kan ileewe naa.
Sanwo-Olu nigba to bawọn akọroyin sọrọ nibi ayẹyẹ naa ni, kikọ ileewe naa nilana igbalode ni lati fidi imọ ẹkọ to dara mulẹ
Ọba Abiọdun Ogunbọ, Ọlọgọmbọ ti ilu Ọgọmbọ dupẹ lọwọ gomina bo ṣe mu ileri rẹ ṣẹ bakan naa ni kabiesi dupẹ lọwọ awọn to wa bawọn ṣajọyọ
                
        

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.