Ọpẹ o,Sanwo-Olu ti bẹrẹ si pin ounjẹ atura fawọn araalu

Ọlaide Gold
       
 Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti ṣiṣọ loju pinpin ounjẹ fawọn eeyan kaakiri ipinlẹ rẹ. Sannde, ọjọ kẹta oṣu yii leto naa bẹrẹ eyi tijọba ṣalaye pe, o ma bu ororo itura si  oju ọgbẹ ti ọwọngogo ounjẹ ati epo bẹntiro dasilẹ nigboro.
Igbesẹ naa wa lara alaalẹ ti gomina  Babajide Sanwo-Olu la kalẹ lati pese gẹgẹ bi atura fawọn araalu.
Gẹgẹ bi ileri ti gomina ṣe, mọlẹbi tiye wọn to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ni wọn maa jẹ anfaani ounjẹ atura naa ti wọn ti ṣe ni iwọn apo keekeke nigbati awọn agbegbe maa gba  tiwọn lapolapo. Awọn ounjẹ koṣeemani tẹnu n jẹ bii, irẹsi,ẹwa ati gaari lo wa nibẹ ṣugbọn awọn apo naa gbewọn to jọju.
Awọn ounjẹ atura yii wa ni ibamu pẹlu erongba gomina naa lati jẹ ki nnkan rọju diẹ atipe ki ipinlẹ Eko tun le rọrun lati gbe fun tonile talejo ni ti ẹdinwo ọwọ ọkọ bogini alawọ bulu tawọn eeyan ṣi n jẹ anfaani ẹ lọwọlọwọ ati itọju ọfẹ fawọn alaboyun lawọn ileewosan ijọba.
Ninu ọrọ ẹ lasiko to bawọn oniroyin sọrọ nibi eto naa to waye nileejọba nilu Ikẹja l'Eko, Sanwo-Olu ni, ogunlọgọ awọn olugbe ipinlẹ naa niwọn maa jẹ anfaani ounjẹ yii,o leto wa fawọn ileeṣẹ nla nla ati ileeṣẹ alabọọde bakan ni iṣẹ ti lọ labẹnu lati rii dajupe awọn ounjẹ naa bọ  sọwọ awọn to nilo ẹ.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.