Lẹ́yìntí rélùweè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ l'Ékòó, Sanwó-Olú ní, iṣẹ́ àkànṣe kò lè sú mi
Ọlaide Gold
Ṣẹnkẹn ninu awọn eeyan n dun lọjọ Mọnde, ọjọ kẹrin oṣu kẹsan-an taa wa ninu ẹ yii ti wọn si bẹrẹ sii kira wọn tayọtayọ. Gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu tiwọn ba kọwọọrin wọkọ pọ lo jẹ ki wọn maa dunnu bẹẹ.
Ọjọ naa ni reluwee ayarabiaṣa tiwọn pe ni Blue Line Light Rail bẹrẹ iṣẹ nipinlẹ Eko.
Ṣaaju akoko yii ni adari ajọ LAMATA, Abilekọ Abimbọla Akinajọ kede iroyin naa fawọn oniroyin ni ibudokọ reluwee naa to wa ni Marina niluu Eko.
Ninu ọrọ ti Sanwo-Olu sọ lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ ki ọkọ to ṣi laarọ ọjọ naa lo ti jẹ ko di mimọ pe, yatọsi reluwee to bẹrẹ iṣẹ yii, ọkọ oju irin mi-in tun maa bẹrẹ iṣẹ kọdun yii to pari, iyẹn ni wọn pe ni Red line light rail.
Kaadi olomi bulu tiwọn kọ cowry si lara ati kaadi igbelu nipinlẹ Eko iyẹn LASSTRA nikan leeyan le fi wọ ọkọ naa gẹgẹ bi gomina ti sọ.
Comments
Post a Comment