Sanwo-Olu yan Gawat ati Ajetunmọbi pada sipo wọn


 Ọlaide Gold

 

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu tun yan Jubril Gawat ati Wale Ajetunmọbi gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin.

Iroyin naa ti olubadamọran agba fun gomina lori ọrọ iroyin,Ọgbẹni Gboyega Akọṣile fi lede lo ti ṣalaye pe awọn mejeeji naa niwọn tẹwọ gba iwe latọdọ ijọba ipinlẹ naa eyi ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba,Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla fọwọsi pe ki wọn pada sipo ki wọn si bẹrẹ iṣẹ lojuẹsẹ.

Gawat, to n ṣakoso iroyin ayelujara ati ọgbọn inu ti ṣiṣẹ pẹlu gomina naa ni saa akọọkọ gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ agba lori ọrọ iroyin nigbati Ajetunmọbi, akọroyin lati ileeṣẹ iroyin beba olojoojumọ The Nation,toun naa ti ba gomina ṣiṣẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ agba lori iroyin apilẹkọ ni wọn ni ki wọn jọ dipo wọn mu ṣinṣin kiwọn si bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ.

Ninu lẹta naa ni, Muri-Okunọla ti ṣapejuwe yiyan pada sipo awọn mejeeji gẹgẹ bi ifọkantan ti gomina ni si wọn nibẹ lo ti gba wọn nimọran pe, ohun tijọba n fẹ latọdọ ẹni ti wọn ba yan sipo ni ẹmi ifọkansin and iṣedeede lẹnu iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ. O wa rọ wọn ki wọn ma ṣe fa sẹyin ninu iṣẹ wọn.


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.