LAWMA máa bẹ̀rẹ̀ sí fàwọn tí kò ní koto ìdalẹ̀si jófin


Ọlaide Gold

Ẹka ilẹẹṣẹ to n mojuto ọrọ kolẹ-kodọti n'Ipinlẹ Eko iyẹn Lagos Waste Management Authority (LAWMA) ti kede erongba rẹ lati bẹrẹ si ti awọn ilegbe atawọn ileeṣẹ aladani kọọkan pa kaakiri agbegbe to wa nipinlẹ naa bẹrẹ lọjọ keje oṣu yii. Igbesẹ naa waye latari bi wọn ṣe kuna lati pese koto idalẹsi eyi tajọ naa ni  ki wọn gbe sojude wọn.
Ọga agba aṣiro owo nileeṣẹ LAWMA, Ọgbẹni Kunle Adebiyi, lo fọrọ naa lede ninu atẹjade kan nibi to ti ṣalaye pe, afojudi awọn olugbe ipinlẹ naa pọ toripe ajọ kolẹ kodọti ti fi aaye silẹ to funwọn lati pese koto idalẹnu ọlọmọri siwaju ileeṣẹ tabi ile wọn ṣugbọn ti wọn ko ṣe bẹẹ. O ni, bi ajọ naa ba ti gunle ipinnu rẹ lati kọ awọn alaigbọran lẹkọọ tawọn tọrọ naa kan si ṣe nnkan to tọ yoo jẹ irorun fun onikaluku bakan naa lo sọ pe igbesẹ naa wa ni ibamu lati gbe ipinlẹ naa sawujọ awọn ipinlẹ to ṣe ara ọtọ lagbaye.

Awọn afojusun ajọ LAWMA lawọn agbegbe bii erekuṣu ati aarin gbungbun Eko atipe ijiya nla ti wa nilẹ fawọn to ba bawọn oṣiṣẹ wọn ja abi di wọn lọwọ lati ṣiṣẹ wọn.
O ṣalaye siwaju sii pe ileeṣẹ LAWMA ti ṣetan lati ṣiṣẹ moriya ju atẹyinwa lọ, bakan naa lo rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati fọwọsowọpọ pẹlu Gomina Babajide Sanwo-Olu lati mu imọtoto ni pataki ki nnkan nipinlẹ naa.
 .     

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.