Ipinlẹ Eko fẹẹ dowopọ pẹlu awọn ileeṣẹ sọdọti-dowo
Ọlaide Gold
Ni bayii ,ijọba ipinlẹ Eko ti pawọpọ pẹlu Orileede Netherlands atawọn ileeṣẹ miiran lati bẹrẹ sii sọ idọti dowo, eyi ti wọn pe ni Lagos Circular Economy ‘Hotspot 2023. Igbesẹ́ yii jẹ ọkan lara erongba gomina Babajide Sanwo-Olu lati mu ọrọ aje ipinlẹ naa lọ soke sii.
Akọwe agba lẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto ayika Dokita Mobọlaji Gaji, lo fọrọ naa lede nibi ipade awọn oniroyin to waye lọjọbọ Tọside nilu Ikẹja. Nibẹ lo ti ṣapejuwe eto sọdọti dowo naa gẹgẹ bi igbesẹ lati sun ipinlẹ Eko siwaju sii atipe yoo koju iṣoro idọti lawọn agbegbe kaakiri ipinlẹ naa.
Gaji ṣalaye pe, eto naa yoo waye lọjọ kẹẹdọgbọn si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii eyi tawọn akopa to le nirinwo yoo ṣafihan awọn iṣẹ wọn bakan naa lawọn eeyan to le lẹgbẹrun kan yoo darapọ mọ irin ajo naa lori afẹfẹ.
Awọn ti wọn kopa ninu ipade naa ni abilekọ Kẹmi Ajakaiye,Ọgbẹni Abayọmi Magbagbeọla ati ọkan lara wọn ọmọ ẹgbẹ eto iṣuna nilẹ alawọ dudu iyẹn African Economy Network, Ọgbẹni Gboyega Ọlọrunfẹmi, wọn ṣalaye pe iru apejọ bayii ti waye lawọn nla nla bii Netherlands, Luxembourg, Germany, Catalonia Spain, ati Dublin, Ireland, ṣugbọn ipinlẹ Eko lo kọkọ ṣeto naa fun igba akọkọ nilẹ Afirika.
Ṣaaju akoko yii ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pe apejọ awọn oniṣowo sọdọti-dowo eyi to waye lọjọ keji oṣu kejila ọdun 2020, latigba naa ni ajọṣepọ to dan mọran ti wa laarin ijọba atawọn olokoowo sọdọti-dowo naa.
Comments
Post a Comment