Sanwó-Olú tún padà yan Táyọ̀ Àyìndé sípò olórí òṣìṣẹ́ rẹ̀



Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu tun pada yan Tayọ Ayinde sipo olori awọn oṣiṣe rẹ, ọdun mẹrin ni ọkunrin naa fi wa nipo ọhun fun saa akọọkọ ti gomina naa fi ṣakoso ipinlẹ naa ṣugbọn oun naa ni wọn tun kede bayii pe ko maa ba iṣẹ rẹ lọ.

Awọn mi-in ti gomina tun yan sipo ni Amofin Bimbọla Salu-Hudeyin, adele ọga agba fun ajọ  eleto ikaniyan, ti wọn n pe ni National Population Commission (NPC) , oun lo wa nipo akọwe agba ijọba bayii nigbati Gboyega Sanyawo naa pada sipo rẹ gẹgẹ bi igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina.

Ninu atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Ọgbẹni Hakem Muri-Okunọla fi lede lo ti ṣapejuwe amofin Bimbọla Salu-Hundeyin,gẹgẹ bi ẹni to kaju iwọn to si mọ nnkan to n ṣe.

Olori awọn oṣiṣẹ gomina, Tayọ Ayinde ati igbakeji rẹ Gboyega Soyannwo ti ṣiṣẹ pẹlu gomina fun saa akọọkọ eyi to bẹrẹ ninu oṣu karun ọdun 2019 to si tẹnubepo l'oṣu karun ọdun 2023.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.