Sanwó-Olú ní kí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ máṣe gùnlé ìyanṣẹ́lódì, Ó ní tiwọn ni Tinúbu n ṣe
Ọlaide Gold
Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu ti gba ẹgbẹ oṣiṣẹ iyẹn Nigeria Labour Congress (NLC) ẹka tipinlẹ naa nimọran ki wọn ma ṣe daṣẹsilẹ gẹgẹ bi apapọ ẹgbẹ naa ṣe leri pe iyanṣẹlodi naa yoo bẹrẹ lọjọru Wẹsidee ọsẹ yii
Sanwo-Olu sọrọ naa lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin isin idupẹ ajọyọ iburawọle to waye lonii, ọjọ Aiku Sannde nileejọsin Cathedral Church of Christ, to wa niluu Marina l'Ekoo eyi to fi lọ fi ẹmi imoore han si Ọlọrun fun bi oun ati igbakeji rẹ Dọkita Ọbafẹmi Hamzat ṣe jawe olubori ninu ibo to kọja lati tukọ ipinlẹ naa fun saa ẹlẹẹkeji. Ibẹ lo ti gba awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ niyanju pe ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ, o ni ki wọn ma ṣẹ gunle iyanṣẹlodi gẹgẹ bi wọn ti kede nitori eree ko le daa ni aarẹ Bọla Tinubu n sa atipe fun anfaani awọn araalu ni owo iranwọ epo tijọba yọwọ kilanko ẹ kuro nibẹ leyiti yoo faaye gbawọn iṣẹ akanṣe kaakiri agbegbe kọọkan lorileede yii
O gba awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa nimọran ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba to wa nibi iṣakoso agbara lọwọlọwọ ki wọn si ṣe suuru fun aarẹ Tinubu ko le farabalẹ pe ọrọ aje orileede yii to ti ṣako lọ pada kawọn araalu le bẹrẹ sii jẹ adun ijọba awaarawa. Ọkunrin akọọkọ nipinlẹ naa ni
ki wọn maṣe gbagbe pe ipinlẹ Eko ni aarẹ ti wa tori naa ṣe ni ki wọn ma a fi adura ran an lọwọ.
Sanwo-Olu ni kiwọn ma ro ti abosi tawọn
oloṣelu kan ki bọrọ naa ti wọn n bẹnu atẹ lu igbese Tinubu bẹẹ gbogbo awọn oludije dupo aarẹ ni wọn ṣatẹnumọ rẹ ninu ipolongo ibo wọn pe owo iranwọ ori epo ni lati lọ sokun igbagbẹ awọn ba wọle ibo nitori naa kawọn oṣiṣẹ ma ro tawọn oloṣelu alabosi ṣugbọn ki wọn faaye silẹ fun ijọba apapọ lati tun orileede yii ṣe.
Comments
Post a Comment