Sanwó-Olú kéde sáà ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá, íléégbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó



Aago mọkanla kọja ogun iṣẹju lọjọ Iṣẹgun Tusidee layẹyẹ naa waye lọfiisi ijọba nilu Ikẹja l'Ekoo, nibẹ ni gomina ipinlẹ naa Babajide Sanwo-Olu ti kede ipele akọọkọ imuṣẹṣe ileegbimọ aṣofin ẹlẹẹkẹwaa nipinlẹ naa nibi ti akọwe ijọba ti bura fawọn aṣofin ogoji.
Ayẹyẹ naa ni Sanwo-Olu lo duro gẹgẹ bi ami itẹsiwaju irinajo oṣelu ipinlẹ naa, o ṣatẹnumọ ojuṣẹ aṣofin gẹgẹ bi opo to gbe ijọba awaarawa duro bakan naa lo rọ wọn ki wọn maa ṣe ojuṣe wọn fawọn araalu
Gomina naa ṣatẹnumọ ọrọ rẹ pe, ireti awọn oludibo rọ mọ awọn aṣofin ti wọn dibo yan lati ṣojuu wọn atipe kawọn aṣofin naa sowọpọ pẹlu ẹka ijọba yooku fun itẹsiwaju ijọba awaarawa. 
  
Sanwo-Olu to ṣapejuwe ipinlẹ Eko gẹgẹ bi awokọṣe sọ pe, irinajo lati saa kẹsan si ikẹwaa to lọ wọọrọwọ laisi idiwọ naa fidi ẹ mulẹ pe nnkan n lọ letoleto nileegbimọ ipinlẹ naa leyi ti yoo mu ki idagbasoke rọrun siwaju sii.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ "A kede saa aṣofin ẹlẹẹkẹwaa nileegbimọ aṣofin ipinlẹ yii lati maa tukọ imuṣẹṣe saa ẹlẹẹkẹwaa lọ fun itẹsiwaju ijọba awaarawa. Igbimọ aṣofin jẹ opo pataki ninu iṣejọba. Awọn araalu nireti ninu awọn aṣoju ti wọn dibo yan sipo nitori naa opo naa ko gbọdọ yẹ  gẹrẹ nitoripe oju gbogbo lo n wo o"
Ọkunrin akọọkọ nipinlẹ naa gbawọn aṣofin naa nimọran ki wọn ṣe eyi to tọ bi wọn ba n ṣe  iyansipo laarin ara wọn. O dupẹ lọwọ awọn aṣofin tiwọn ba a ṣejọba saa akọọkọ bẹẹ lo rọ awọn tiwọn ṣẹṣẹ ṣebura wọle fun saa ẹlẹẹkẹwaa ki wọn ṣoju ẹkun idibo wọn daradara.
Ọmọleegbimọ ogun ninu awọn aṣofin tẹlẹ lo pada fun saa ẹlẹẹkẹwaa yii nigbati ogun aṣofin yooku jẹ aṣẹṣẹ yan,ẹgbẹ oṣelu All  Progressives Congress (APC) ni aṣofin mejidinlogoji nigbati ẹgbẹ oṣelu alatako aṣofin meji.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.