Sanwó-Olú fọwọ́sí gbígba ìwé ẹ̀rí aṣàfihàn ẹni tó lọkọ̀ l'Ékòó

Ọlaide Gold
     
Ẹgbẹrun kan naira lowo tawọn eeyan ma
san bayii fun iwe ẹri emi ni mo lọkọ. Akọwe Agba nileeṣẹ ijọba to n mojuto lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Abdulhafiz Toriola, lo ṣiṣọ loju ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun Tuside Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu yii ninu ipade kan to waye ninu gbọngan awọn oniroyin nilu Alahusa Ikẹja l'Ekoo.
Gẹgẹ bi alaye rẹ, igbesẹ naa waye lati daabobo dukia ati ẹmi awọn araalu. Iwe ẹri naa ti wọn pe ni Proof of Ownership Certificate (PoC) tawọn ọlọkọ yoo ma gba lọdọọdun naa wa ni ibamu labẹ ofin akoyawọ eto irinna apapọ ọdun 2012 eyi to fidi ẹ mulẹ pe iwe ẹri emi ni mo lọkọ yoo wa gẹgẹ bi ijẹrisi, afikun kan tun wa ninu ofin naa to tọka si pe ẹka naa yoo ṣe agbekalẹ atẹ kan ti yoo ṣafihan onka ọkọ atawọn awakọ kaakiri orileede yii.
Iwe ẹri yii bawọn ọlọkọ ba ti tọwọbọwe to yẹ tan lori ẹ lo maa duro gẹgẹ bi aṣafihan ẹni to lọkọ toripe gbogbo idanimọ aṣapejuwe lo maa wa ninu ẹ koda titi dori irufẹ ọkọ to jẹ ati ọdun ti wọn ṣe e jade. 
​Nii bayii gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti fọwọsi ki gbigba iwe ẹri aṣafihan ẹni to lọkọ naa  bẹrẹ nipinlẹ rẹ, idi si niyẹn ti apejọ oniroyin naa fi waye lati jẹ kawọn araalu le mọ pe aabo wọn jẹ ijọba apapọ logun.





Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.