Sanwo-Olu ati Hamzat ṣayẹyẹ fun MKO Abiọla
Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lọjọ Aje Mọnde rọ awọn olugbe ipinlẹ naa pe ki wọn daabobo ijọba awaarawa.
Igbakeji gomina naa,Dokita Ọbafẹmi Hamzat lo gbẹnu gomina sọrọ yii nibi ayẹyẹ iranti ọgbọn ọdun ti wọn fagile esi ibo oloogbe MKO Abiọla.
Akojọpọ ẹgbẹ Yoruba kan ti wọn pe ni Alliance for Yoruba Democratic Movement ṣe agbatẹru rẹ nileejọsin St Leo’s Catholic Church lagbegbe Ikẹja l'Ekoo. Nibẹ ni Hamzat, ti sọ pe, ifọkansin ati igbagbọ ninu ijọba awaarawa lo le gbe orileede leke
Awọn ẹṣọ alaabo to wa nibẹ lọjọ naa ni ẹgbẹ Oodua People's Congress reformed,OPC New Era,Agbekoya atawọn mi-in
Comments
Post a Comment