Ọ̀WỌ́NGÓGÓ EPO: Hamzat korò ojú sáwọn alágbàtà tó sọjà dọ̀wọ́n


Ọlaide Gold
Igbakeji gomina ipinlẹ Eko,Ọbafẹmi Hamzat ti rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa lati farada bi ijọba apapọ ṣe yọwọ kilanko rẹ kuro ninu iranwọ owo ori epo. Hamzat sọrọ yii lorukọ gomina Babajide Sanwo-Olu lasiko to ṣabẹwo sawọn ileepo kan laisọtẹlẹ, nibẹ lo ti gba awọn araalu nimọran lati ṣe suuru pẹlu ijọba apapọ nitoripe ija mẹkunnu naa nijọba  aarẹ Bọla Tinubu n ja.
Ọbafẹmi  Hamzat sọpe, ida mẹtala pere lawọn mẹkunnu ko ninu owo ori epo tiwọn n yọ nigba tawọn tọrọ naa kan gbọngbọn ni wọn n da ida mẹtadinlaadọrun sapo ara wọn.
Awọn ileepo tigbakeji gomina naa ṣabẹwo aisọtẹlẹ si ni ileepo nla NNPC to wa lojuna Kingsway n'Ikoyi,NNPC to wa lojuna Awolọwọ ni Ọbalende, Total Energy Sura. Ọkunrin naa sọ pe tawọn araalu ba fọwọsowọpọ pẹlu ijọba aarẹ Aṣiwaju Bọla Tinubu ,owo iranwọ ori epo tawọn eeyan kan n ṣe bo ti wu wọn yoo jẹ lilo lawọn ẹka mi-in  bii eto ẹkọọ,ilera atawọn ohun amayedẹrun mi-in.
Ṣaaju akooko yii ni gomina Sanwo-Olu ti bẹnu atẹ lu bawọn alagbata epo ṣe sọ ọja dọwọn ni kete ti aarẹ Bọla Tinubu kede pẹlu alaye pe ko si aaye fun iranwọ owo ori epo ninu iwe tijọba ana gbe le oun lọwọ nitori naa kosi nnkan to n jẹ owo iranwọ epo mọ.
Gomina Sanwo-Olu ni ṣe lawọn alagbata epo fi abosi gọ sabẹ ikede yii ti wọn wa n ṣe bi ẹnipe kinni naa bawọn lojiji bẹẹ wọn ti mọ tẹlẹ.
Ọrọ ti gomina sọ yii waye lasiko ti Olori oṣiṣẹ ipinlẹ naa,Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla mu gomina ati igbakeji rẹ yika ileeṣẹ ijọba ni kete ti wọn bẹrẹ iṣẹ fun saa ẹlẹẹkeji ibẹ ni gomina ti koro oju si bawọn alagbata epo bẹntiro ṣe gọ sabẹ ikede aarẹ ti wọn si bẹrẹ sii ta jaala epo lowo to gaara.

Gomina wa rọ awọn olugbe ipinlẹ naa pe ki wọn maa ba iṣẹ oojọ wọn laisi wahala toripe ko le da a ni nnkan tijọba to wa nibẹ bayii n ṣe. abẹwo sawọn ẹka ileeṣẹ ijọba bii ẹka to n ri sọrọ awọn obinrin ati  ironilagbara iyẹn Ministries of Women Affairs and Poverty Alleviation (WAPA),ẹka to n mojuto eto iṣuna ati okoowo, Economic Planning and Budget ati ẹka to n ri sọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke agbegbe, Youth and Social Development ni gomina naa sọ pe o wa ni ibamu lati ṣe moriya fawọn oṣiṣẹ ati lati tẹsiwaju sii ninu ilana igba-muṣẹṣe.

O ni, ‘Akitiyan wa ni lati faaye silẹ fun ajọṣepọ to dan mọran fun itẹsiwaju awọn iṣẹ akanṣe taa ti bẹrẹ tẹlẹ ati lati jẹ ko di mimọ fun gbogbo oṣiṣẹ pe iṣẹ naa ti bẹrẹ niyẹn atipe oṣiṣẹ kọọkan gbọdọ mu iṣẹ rẹ ni Pataki. 



Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.