Faṣọla ati Ambọde ba Sanwo-Olu gba Aarẹ Tinubu lalejo l'Ekoo

Ọlaide Gold

Gbogbo eeyan to pesẹ sileejọba ni Marina l'Ekoo niwọn fidunnu han nigbati wọn ri bi gomina tẹlẹ nipinlẹ naa,Ọgbẹni Akinwunmi Ambọde ṣe wa fẹrin atọyaya pade aarẹ Bọla Tinubu.

Gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu lo gba aarẹ lalejo nileejọba ni  Marina. Nibẹ ni aarẹ ti bawọn araalu sọrọ pe oun ko nii ja wọn kulẹ toripe ọrọ aje orileede yii yoo lọ soke sii lasiko iṣejọba oun.
Abẹwo akọọkọ aarẹ ree si ipinlẹ Eko latigba ti wọn ti bura wọle fun lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun yii gẹgẹ bi aarẹ orileede Naijiria. Ọdun ileya lo gbe e wa s'Ekoo.

Ninu ọrọ ti aarẹ sọ lo ti sọ pe 'Gomina Ipinlẹ Eko tẹlẹ, Babatunde Faṣọla lo sọ fun mi pe bi  mo ba wa ninu baluu agberapa, ki n ma bojuwo isalẹ toripe ọpọlọpọ koto ati gegele lo wa lojuna to n fẹ amojuto , mo si ti ri gbogbo ẹ, a maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn gomina ipinlẹ  kọọkan lati ṣe atunṣe awọn ojuna naa ki
 ọrọ aje le rọju.
Sanwo-Olu ninu ọrọ tiẹ dupẹ lọwọ awọn araalu fun atilẹyin wọn lati gbe aarẹ Tinubu depo bẹẹ lo rọ wọn pe aarẹ tun maa nilo atilẹyin wọn siwaju sii
Awọn eeyan pataki ti wọn wa nibẹ ni igbakeji aarẹ Kashim Shetimma, iyawo aarẹ abilekọ Olurẹmi Tinubu, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ ti Godswill Akpabio lewaju wọn,awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju atawọn gomina bii AbdulRahman AbdulRasaq tipinlẹ Kwara, Dapọ Abiọdun nipinlẹ Ogun, Hope Uzodimma tipinlẹ Imo, Abdullahi Sule Nasarrawa, Babagana Zulum Borno, Alex Otti Abia.
Awọn yooku ni paadi Hyacinth Alia Benue, Bassey Otu Cross River, Duoye Diri Bayelsa, Yahaya Bello Kogi adele gomina ipinlẹ Ondo Lucky Aiyedatiwa,igbakeji gomina ipinlẹ Eko Ọbafẹmi Hamzat, gomina ipinlẹ  Eko tẹlẹ Akinwunmi Ambọde, Abdullahi Ganduje Kano ati igbakeji gomina ipinlẹ Ekoo,Ọgbẹni Fẹmi Pedro.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.