Sanwó-Olú ṣèbúra fáwọn akọ̀wé àgbà mẹjọ l'Ékòó
Ọlaide Gold
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣebura fawọn akọwe agba tuntun mẹjọ nileeṣ ijọba towa ni Alahusa nilu Ikẹja.
Ninu ọrọ ti olori awọn oṣiṣẹ, Ọgbẹni Hakeem Muri- Okunọla sọ nibi ayẹyẹ naa to waye ninu gbọngan ileejọba lọjọbọ Tọsidee, ọjọ kejidinlogun oṣu yii lo ti gboṣuba kare fun gomina ọhun fun igbesẹ itẹsiwaju to gbe nipa bo ṣe yan awọn ti ipo naa tọ si laifi igba kan bọ ọkan ninu.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, awọn akọwe agba mẹjẹẹjọ naa ni iyansipo awọn kan ti waye latojọ kejilelogun oṣu kẹsan ọdun to kọja ti tawọn kan tun waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kin-in-ni ati ọjọ kẹjẹ oṣu kẹrin ọdun yii ki gomina to pinnu lati bura wọle funwọn ninu oṣu karun ọdun yii
Awọn akọwe agba tiwọn bura fun naa ni ,Ọgbẹni Adewuyi Moshood Adewale gẹgẹ bi ayẹwe owo-wo agba, Ọgbẹni Adebowale Adeoye Bashir,ẹka eto ẹkọ, abilekọ Patunola-Ajayi Olayinka, ẹka amuṣẹṣe, abilekọ Yusuf Shareefah Adejoke,ẹka ẹkọ ipin kẹfa, Ọgbẹni Amuni Abayọmi Mustapha,ẹka ẹkọ ipin karun,awọn yooku ni Ọgbẹni Ọbadina Akinbọde,ẹka alabojuto ijọba ibilẹ,abilekọ Olushekun Bibilọmọ Ọlayide,ẹka alabojuto imuṣẹṣe ijọba ibilẹ ati abilekọ
Akanbi Adenikẹ Ganiat, Ọfiisi adari awọn oṣiṣẹ.
Bakan naa ni gomina ti ṣetan lati nawọ aṣayan naa de ẹka ilera, o ni eyi yoo waye latari iṣẹ moriya tawọn oṣiṣẹ eleto ilera n ṣe leyi ti yoo jẹ kawọn dọkita kan tun darapọ mọ awọn akọwe agba nileejọba.
Gomina Sanwo-Olu ki awọn akọwe agba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣebura fun naa ku oriire bakan naa lo gba òwọn niyanju lati ṣiṣẹ wọn pẹlu otitọ inu sijọba ipinlẹ Eko ati orileede Naijiria lapapọ.
Comments
Post a Comment