Sanwó-Olú gbàlejò àwọn ọmọleégbìmọ̀ aṣojuṣofin àṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn níléèjọba ní Marina


Ọlaide Gold

Lọjọ abamẹta Satide to kọja , ni Gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu,gbalejọ Ọnarebu ti wọn fa kalẹ gẹgẹ bi abẹnugan ileegbimọ aṣoju,Tadujeen Abbas atawọn marundinlogoji ninu awọn ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin aṣẹṣẹ dibo yan latinu ẹgbẹ APC,PDP,LP ati APGA.

Abẹwo naa to waye nileejọba to wa ni Marina l’Ekoo ni Ọnarebu Tajudeen Abbas, Aṣoju ẹkun idibo Iwọ Oorun Ariwa nipinlẹ Kaduna ṣapejuwe gẹgẹ bi akọọkọ iru rẹ, O ni ipinlẹ Eko lawọn ti bẹrẹ irinajo tawọn gunle naa lati mu ki iṣejọba aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan,Aṣiwaju Bọla ahmed Tinubu le jẹ eyi ti yoo jẹ itura fawọn eeyan jakejado orileede Naijiria. O tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe, ọna lati mu ilana igbaṣejọba rọrun lo jẹ kawọn faaye gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako bii,ẹgbẹ Oṣelu Labour,APGA ati PDP laaye lati darapọ mọ irinajo naa tori itọ teeyan ba tọ sojukan nii ho ọṣẹ atipe agbajọ ọwọ ni eeyan fi n sọya.

Ọnarebu naa ni, lootọ ẹgbẹ ti fa awọn kalẹ tawọn kan si ti fọwọ si i ṣugbọn to ba wa dipe idibo yoo waye lati yan abẹnugan ileegbimọ aṣojuṣofin, o daju pe gomina naa yoo ba awọn akẹgbẹ rẹ niha Ila Oorun sọrọ kawọn le ri oju rere awọn aṣoju wọn.

Ninu ọrọ tiẹ,Ọnarebu Ben Kalu,  Aṣoju Gusu-Iwọ Oorun Abia ti wọn tun dabaa gẹgẹ bii igbakeji abẹnugan ileegbimọ aṣojuṣofin dupẹ lọwọ Gomina Sanwo-Olu, O lọkunrin naa jẹ apẹẹrẹ rere fawọn akẹgbẹ rẹ latari akitiyan rẹ ṣaaju, lakooko ati lẹyin idibo ti nnkan si ṣenuure fun ẹgbẹ Oṣelu APC.Ṣe ti ọrọ aje ipinlẹ naa ti ko jo ajorẹyin ni ka sọ ni abi tawọn iṣẹ akanṣe aritọkasi ti Gomina naa ṣe laisi ojuuṣaju. Kalu ni, itẹsiwaju Orileede Naijiri lo jẹ ijokoo aṣojuṣofin ẹlẹẹkẹwaa lorileede yii logun, tori ẹ lawọn ṣe mu ajọṣepọ ni koko tawọn si ti ṣetan lati kọmọlupọ pẹlu awọn ẹgbẹ alatako fun itẹsiwaju rere. O ni ileegbimọ aṣofin to ba n bara wọn ja latari ẹgbẹ aṣeyatọ ko ni ifẹ orileede denu toripe asiko to yẹ ki wọn ṣe ohun iwuri ni wọn maa fi pagbo ija ati idarudapọ.   

Nigba to fesi sọrọ wọn,Sanwo-Olu ki awọn aṣoju naa kaabọ sileejọba ipinlẹ Eko bakan naa lo ki wọn ku oriire bi wọn ṣe jawe olubori ninu ibo to kọja. Gẹgẹ bi ọrọ rẹ ‘Mo ti ṣewadii lori awọn abẹnugan mejeeji ni kete ti wọn kede orukọ wọn, mo si ri pe wọn kaju iwọn eyi lo fun mi ni idaniloju pe, aṣayan lawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ẹlẹẹkẹwaa tawọn araalu ṣẹṣẹ dibo yan lorileede yii, o si dajupe wọn ma ṣoju ẹkun wọn idibo daradara.

Sanwo-Olu gba awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC nimọran pe ki wọn ṣe ara wọn loṣuṣu ọwọ ki wọn si faaye ajumọṣe silẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu alatako ki nnkan le lọ bo ti yẹ nitori ile to ba to nii tẹsiwaju. Gomina naa loun yoo sa ipa lati ri i dajupe ọrọ naa pada ri bi wọn ti n fẹ toripe ko sẹni ti ko nifẹẹ ilọsiwaju ninu awọn akẹgbẹ oun. O wa rọ gbogbo ọmọ ileegbimọ aṣojuṣofin ti wọn wa nibi ipade naa ki wọn mu ifẹ awọn eeyan ti wọn fẹẹ lọ ṣoju fun ni pataki toripe ẹniti inu araalu ba dun si ni inu Ọlọrun ọba paapaa yoo dun si.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.