Oríṣìíríṣìí ètò ni a ti là kalẹ̀ fún ayẹyẹ ìbúra Sanwó-Olú-Ọmọtọṣọ


 Ọlaide Gold

Lọjọ Ẹti Furaide,ọjọ kọkandinlogun ni Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Eko,Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ,  ṣalaye awọn alakale eto ayẹyẹ ipadabọ sipo Sanwo-Olu lẹẹkeji yoo ṣe lọ. O sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nileejọba  ni Alahusa nilu Ikẹja.

Gẹgẹ bi ọrọ kọmiṣanna naa to tun jẹ alaga igbimọ amuṣẹṣe ipadabọ gomina naa, oriṣiiriṣii ayẹyẹ ni yoo waye ṣaaju ati lẹyin eto ibura ẹlẹẹkeji fun gomina ipinlẹ Eko,Ọgbẹni Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, leyi ti gbogbo ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ naa yoo ni ipa pupọ lati ko. Ijọba ibilẹ ipin marun  to wa kaakiri ipinlẹ naa lawọn eto oriṣiiriṣii ti wọn ti la kalẹ naa yoo ti waye bẹrẹ lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu yii nibi tawọn ọdọ yoo ti ṣide eto naa leyi ti ko yọ awọn tẹya ara pe nija silẹ,ọjọ kẹtadlelogun ni akanṣe idanilẹkọọ ti yoo waye ni gbọngan Muson Center  latẹnu Ọjọgbọn Adigun Agbaje, nibẹ ni wọn yoo ti ṣiṣọ loju iwe kan to sọ nipa akitiyan gomina Sanwo-Olu ati ilana iṣejọba rẹ ni saa akọọkọ bakan naa ni wọn maa ṣafihan ere oniṣe to sọ nipa ibagbepọ awọn eeyan laarin ipinlẹ naa.

Eto naa ko nii yọ awọn ogo wẹẹrẹ silẹ layajọ awọn ewe iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn nibi tawọn ewe kaakiri ipinle Eko yoo ti kopa ninu awọn ọlọkan-o-jọkan nnkan ti wọn fẹran lati maa ṣe.Ọjọ kejidinlọgbọn ni igbaradi lati ki ọjọ kọkandinlọgbọn kaabọ maa bẹrẹ. Ayẹyẹ ipadabọsipo gomina yoo waye ninu ọgbọ Tafawa Balewa Square nibiti gomina yoo ti gba ọpa aṣẹ ma a baṣẹ rẹ lọ fun saa keji. Oriṣiiriṣii oro oju ni wọn maa ṣe foju lọjọ naa toripe awọn ere ibilẹ yoo waye loriṣiiriṣii, lọjọ Furaide to tẹlee ni wọn maa lọ ṣadura ni mọṣalaṣi Jimọ ninu Alahusa  nigbati isin idupẹ yoo waye lọjọ Aiku Sannde.

Gbogbo ayẹyẹ tawọn igbimọ amuṣẹṣe ipadabọ sipo gomina ti la kalẹ naa yoo waye lawọn ijọba ibilẹ marun bii Ikẹja,Badagry,Ẹpẹ,Ikorodu ati Isalẹ Eko kawọn eeyan le lọ ṣoro oju foju lawọn ijọba ibilẹ to ba sun mọ wọn.

Ọmọtọṣọ lo asiko naa lati ṣalaye awọn iṣẹ akanṣe ti Gomina Sanwo-Olu gbe ṣe laarin saa akọọkọ to fẹẹ tẹnu bepo yii, O ni ,iṣẹ akanṣe ọkọ oju irin Blue Line Rail tawọn eeyan maa bẹrẹ sii ṣiṣẹ nibẹ laipẹ kọja afẹnusọ bakan naa ni Red Line Rail ku diẹ ko pari, ara ọtọ ni idikọ ọkọ oju omi nla nla iyẹn Lekki Deep Sea Port ti ogunlọgọ eeyan yoo bẹrẹ sii ṣiṣẹ nibẹ bakan naa ni ileeṣẹ Irẹsi n’Imọta iyẹn Imọta Rice Mill, lai gbagbe ẹka eto ilera nibiti gomina ti kọ ileewosan mẹrin fun awọn oloyun ati ọmọ wẹwẹ iyẹn Mother & Child Centers.

Gomina Sanwo-Olu pari ojuna to lọ si Ṣomolu,Ikẹja,Agege bakan naa lo ṣatunṣe awọn ojuna mọkanlelọgbọn lawọn agbegbe bii Ojokoro,Badagry,Ikorodu bakan naa lawọn iṣẹ akanṣe miiran ṣi n lọ lọwọ leyi ti gomina yoo pari ninu saa ẹlẹẹkeji. O ni gbogbo awọn nnkan tawọn olugbe ipinlẹ Eko ro pọ niyẹn ti wọn fi jade lọpọ yanturu lati fi ibo gbe Sanwo-Olu wọle lẹẹkan si i.



Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.