Nitori ipo aarẹ ileegbimọ aṣofin,awọn ọmọ ẹgbẹ bẹ Sanwo-Olu lọwẹ

Ọlaide Gold

 
Iroyin naa ko jẹ tuntun mọ pe ija nla n lọ lọwọ laarin awọn aṣofin aṣẹṣẹ dibo yan ilẹẹwa paapaa julọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Sẹnetọ Godswill Akpabio lati ẹkun idibo Gusu-Gusu lawọn akẹgbẹ rẹ to si lẹyin lasiko ti aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan lọ ṣi iṣẹ akanṣẹ kan nipinlẹ Rivers.
Igbesẹ yii ni wọn lo bawọn aṣofin kan ninu ti wọn fi tọ ilẹ la, wọn lawọn o faramọ Akpabio rara, ni kinni ọhun wa di oniga muga laarin wọn.

Ninu ọrọ Sẹnetọ to lewaju lasiko tiwọn ṣabẹwọ si gomina Eko, Ọnarebu Ali  Ndume sọ lo ti ṣalaye pe, oun gan alara  wa ninu awọn to fi erongba rẹ han lati jẹ abẹnugan ileegbimọ aṣofin ṣugbọn nigbati aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu ni  koun juwọsilẹ fun Akpabio atipe ki oun lewaju ipolongo f'ọkunrin naa gẹgẹ bi aarẹ ile aṣofin agba loun ti bẹrẹ iṣẹ,idi si niyẹn tawọn fi gbe igbesẹ lati to ile ko gun rege
Godwill Okpabio ni tiẹ dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ aṣofin naa fun atilẹyin wọn, o gboṣuba kare fun Sanwo-Olu fun aṣeyọri rẹ nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, Ọlọrun lọwọ si irinajo oṣelu to fẹẹ gba akoso ijọba lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii toripe akanda ẹda ati ayanfẹ Ọlọrun bi Aṣiwaju Tinubu nikan lo le bori ogun ibo to kọja. Ọkunrin naa ni iyalẹnu lo jẹ pe ẹnikan le bori gbogbo pampẹ tawọn ọta dẹ silẹ bi ogun ẹsin, ẹlẹyamẹya, ọwọngogo owo lasiko idibo, ọwọngogo epo bẹntiro ati inunibi ti akanda yii tun bori laarin ọta,laarin ẹgan.
Ẹni tawọn akẹgbẹ rẹ to si lẹyin gẹgẹ bi aarẹ ileegbimọ aṣofin agba naa sọ pe, awọn aṣofin to fi ifẹ han si oun ṣe bẹẹ nitoripe wọn nifẹẹ orileede dọkan tori ko nii dara bi idarudapọ ba wa ninu ile aṣofin bakan naa lo jẹjẹ lati ṣiṣẹ pẹlu ootọ inu bi ori ba gbe oun depo naa. O ni aridaju ti wa pe didun ni ọsan yoo so, awọn aṣofin mọkandinlaadọrin ni wọn ti kede atilẹyin foun atipe ki oṣu kẹfa to pe,awọn aṣofin ti yoo darapọ mọ ọkọ naa ma ju  bẹẹ  lọ.        Sanwo-Olu ṣapejuwe Akpabio gẹgẹ bi  ọlọpọlọ pipe ati ẹni to tọ lati di gbohun-gbohun  ileegbimọ aṣofin ẹlẹẹkẹwaa lorileede yii mu. Gomina naa gba awọn aṣofin  aṣẹṣẹ dibo yan  naa niyanju ki wọn ṣoju awọn eeyan wọn daadaa. 
Ọnarebu Ẹṣinlokun lo kadii ọrọ naa nilẹ, o dupẹ lọwọ gbogbo awọn aṣofin ẹgbẹ ọṣelu kọọkan to wa sibi ibẹwo naa , o ṣi ṣeleri atilẹyin fun ikọ to wa lorukọ gomina. Awọn eekan ti wọn tun wa nibẹ ni Sẹnetọ tẹlẹ, Musiliu Obanikoro, Sẹnetọ Ganiu Solomon, SẹnetọTokunbo Afikuyọmi atawọn mi-in.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.