Ẹ bawa daabobo Tinubu o,Adesope, Ọga awọn OPC rawọ ẹbẹ sajọ DSS

Ọlaide Gold

Aarẹ ẹgbẹ Oodua People's Congress  Reformed,Oloye Oludare Adesope ti bẹ ajọ alaabo ọtẹlẹmuyẹ ilẹẹwa atawọn igbimọ amuṣẹṣe fun iṣipopada iyẹn transition committee pe ki wọn mu ọrọ aabo aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan,Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni pataki ni bayii ti Tinubu ti di jigi ẹlẹgẹ iyebiye lorileede yii. Adesope ni,lilọ bibọ rẹ gbọdọ jẹ ara ọtọ atipe aabo to nipọn lo tọ si i bayii toripe eera ko gbọdọ ra a , ṣe ni ki wọn ṣe ọrọ aabo rẹ ni oju ni alakan fi n ṣọri
Ọga awọn OPC naa sọrọ yii ninu iwe kan to fi lede fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta Satide, nibẹ lo ti ṣalaye pe latigba ti ori ti gbe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa depo to ga julọ lorileede yii lawọn kan ti n ṣe inunibini si i latari bi wọn ṣe jabọ ninu ibo naa koda awọn ọmọlẹyin wọn paapaa n petepero bi iṣakoso ijọba naa ko ṣe ni bọ sọwọ Tinubu ṣugbọn gbogbo awijare wọn ko ba ofin ilẹẹwa mu.
Adesope ni, bayii ti aala ti fi oko ọlẹ han ti Aṣiwaju ti ṣiwaju gbogbo wọn, ṣe lo yẹ ki wọn gba kamu amọ ṣeni wọn n gbe iroyin buruku pooyi ẹnu kiri nipa aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan naa leyi to lodi si ofin ilẹẹwa.O wa gba a ladura pe Ọlọrun yoo gbakoso  ọjọ  kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun yii nigbati wọn ba gbe ọpa aṣẹ iṣakoso ijọba  le Tinubu lọwọ atipe orileede Naijiria yoo darapọ mọ awọn orileede aṣiwaju lasiko ijọba rẹ

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.