Àsìkò Tinubu máa sàn wá lórílèèdè yìí,ẹ lọ fọkàn balẹ̀-Adésopé OPC Reformed


Ọlaide Gold

 

Oriire nla ni ohun to ṣẹlẹ si wa lorileede yii, ṣe lo yẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria nilẹ yii ati loke okun gbe igba ọpẹ nitoripe a ti yan ọlọpọlọ pipe ti yoo tukọ orileede yii gẹgẹ bi aarẹ ninu irinajo oṣelu ẹlẹẹkarun ta a wa ninu ọkọ rẹ bayii. Oloye Dare Adesope,aarẹ ẹgbẹ Oodua People’s Congress Reformed lo sọrọ yii ninu iwe kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Satide.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ṣe lo yẹ ki a tibi iṣana kiye soogun, ẹnikan sọrọ pẹlu igboya, o ni’Emi lo kan’ Olodumare si ba a faṣẹ si i. Bo tiẹ jẹpe awọn ogun kan dide si i, lasiko tawọn eeyan n reti ati dibo nijọba apapọ deede paarọ owo naira, ko sowo ko sepo bẹntiro, ọwọngogo ni gbogbo nnkan lasiko yẹn, wọn ṣe eyi lati doju ibo rẹ ru ṣugbọn sibẹ Aṣiwaju Tinubu tun fẹyin awọn alabosi janlẹ, oun lo pada jawe olubori.

 

Adesope ni, oun o ri iru ogun to dide si Tinubu ri, awọn ọmọ bibi ilẹ Yoruba kan paapaa naa lọ dapọ mọ awọn atọhunrinwa, wọn dide ogun si i ṣugbọn sibẹ ko jẹ ki itakun wọn kọ oun lẹsẹ, ṣe lo gbajumọ ibi to n lọ titi to fi jawe olubori ninu ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun yii. ‘Ni kete ti wọn kede orukọ Tinubu gẹgẹ bi aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan, awọn kan tun bẹrẹ si i riran ekee, wọn ni kinni naa ko le tẹ ẹ lọwọ, ko si ohun ti wọn ko sọ tan titi tọjọ naa fi pe.

Ni bayii tọpa aṣẹ ti tẹ Tinubu lọwọ, ọga OPC naa sọ pe, ki Aṣiwaju Tinubu foju iwoye wo bi nnkan ṣe n lọ lati ibẹrẹ, bawọn kan ṣe maa lọ ko ara wọn jọ lati maa ṣiṣẹ tako aarẹ to ba wa nile agbara, wọn le lọ da ẹgbẹ jagidijagan kan silẹ, O ni ki aarẹ tuntun naa mu eto aabo ni pataki ṣugbọn ko ma jẹ awọn ẹṣọ alaabo ijọba nikan niwọn maa fi aabo orileede yii si lọwọ . ‘Ẹgbẹ OPC ti ṣetan lati daabobo ilẹẹwa lọwọ awọn to ba n gbero ibi, awọn ọmọ ẹgbẹ wa pọ kaakiri orileede yii ti wọn si ṣetan lati daabobo ilẹẹ wọn lọwọ awọn ọta ilu.

Nitẹsiwaju ọrọ rẹ,Adesope ṣalaye pe, awọn ọta ilọsiwaju ti wọn ko fẹ ki Naijiria darapọ mọ awọn aṣiwaju orileede lagbaye ni wọn tako iyansipo Tinubu toripe wọn ti mọ pe ọlọpọlọ pipe ni,ijọba rẹ si maa yatọ koda awọn eeyan maa fẹẹ sọ pe ko ma kuro nibẹ ṣugbọn awọn arijẹ nidi ibajẹ ti wọn o fẹ ki orileede yii toro ni wọn gbe ogun dide sii. ‘Mo fẹẹ gba aarẹ tuntun niyanju ko ba wa ṣi awọn odi ilu nitoripe ọrọ aje orileede ko le lọ deede bawọn odi ilu ba wa ni titi pa bakan naa ni kiṣẹ wa lọpọ yanturu fawọn ọdọ,ainiṣẹ lo jẹ kawọn kan fa oju wọn mọra lasiko ibo,ọpẹlọpẹ ifẹ ti Ọlọrun ni si orileede yii to fi jẹ ki ibo naa ja sọwọ aṣiwaju rere awọn ọdọ fẹẹ le ba kinni ọhun jẹ ṣugbọn bi ọwọ wọn ba di ti wọn niṣẹ iru nnkan bẹẹ ko nii ṣẹlẹ lọjọ iwaju. Mo ki gbogbo ọmọ orileede yii ku oriire ti aarẹ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.   


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.