Sanwo-Olu tun fitan balẹ n'Ikorodu pẹlu iṣẹ akanṣe
Ọlaide Gold
Ṣẹnkẹn ni inu awọn olugbe ilu Ikorodu n dun lọjọ Ẹti Fraide,ọjọ kọkanlelọgbọn ọsẹ to kọja, Gomina ipinlẹ Ekoo,Bababtunde Sanwo-Olu lo dẹrin pa ẹẹkẹ wọn. Gomina naa ṣiṣọ loju ọna gigun oni kilomita meji aabọ lopopona Ọba Sẹkumade lagbegbe Ipakodo nilu Ikorodu ati atunkọ ọna T.O.S Benson,eyi to fi sọri ileri to ṣe fun wọn lasiko ipolongo saa akọọkọ rẹ.
Sanwo-Olu ṣe atunṣe ojuna naa lati jẹ ki lilọ bibọ ọkọ jẹ irọrun fawọn olugbe agbegbe bii Ibeṣe, Igbogbo-Baiyeku, Ebute Ipakodo, aarin gbungbun Ikorodu ati etikun Ipakodo.
Iṣẹ yii jẹ akọọkọ iru ẹ ti gomina naa yoo ṣe lẹyin idibo to gbe e wọle lẹẹkeji ,O fi asiko naa dupẹ lọwọ awọn eeyan fun igbagbọ ti wọn ni ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati ireti ti wọn ni ninu oun siwaju si i.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, O ni: “ A wa siluu Ikorodu lonii lati fi idunnu wa han si gbogbo ẹyin eeyan wa , ibi tẹẹ to si lasiko idibo jẹ iwuri a si mọ ọ loore. Iṣẹ akanṣe yii jẹ ọna lati fi ibaṣepọ to wa laarin awọn eeyan ilu Ikorodu ati ijọba ipinlẹ Ekoo mulẹ siwaju si i’.
Ṣiṣi aṣọ loju ojuna Ọba Sẹkumade ati atunkọ ojuna T.O.S Benson fidi iṣejọba Sanwo-Olu mulẹ gẹgẹ bi eyi to muna doko. Gomina naa wa ṣeleri pe ko si agbegbe kankan toun maa ta danu l’Ekoo nitoripe gbogbo ọna ti ko da a to ni ijọba oun yoo mojuto.
Sanwo-Olu sọ pe, ilu Ikorodu ati agbegbe rẹ yoo tubọ jẹ anfaani ijọba oun siwaju sii nipa ṣiṣe iṣẹ akanṣe to joju sawọn agbegbe naa, O mu u da wọn loju pe, awọn kọngila ti wọn gbe awọn iṣẹ akanṣe fun kaakiri ilu Ikorodu ti tọwọ bọwe pe awọn ko nii fi iṣẹ naa falẹ nitori naa ki wọn ma ṣe mikan rara.
Ẹwẹ gomina Sanwo-Olu tun jẹ ko di mimọ pe awọn iṣẹ akanṣe yooku lawọn ojuna bii Agric-Iṣawọ yoo pari laipẹ bakan naa lo sọ pe, awọn kọngila yoo yawọ si ojuna Ewu Ẹlẹpẹ si Gbẹrigbẹ, Igbogbo si Bọla Ahmed Tinubu ati Adamọ-Agunfoye.
Lakotan, o ni awọn kọngila yoo yawọ si iṣẹ ojuna Igbogbo-Baiyeku eyi ti yoo ṣe atọkun awọn ojuna yooku wọnu ara wọn.
Comments
Post a Comment