Ọlọrun lo n gbeni depo, ki i ṣeniyan-Lai Muhammed
Minista fun ọrọ iroyin ati aṣa, Lai Muhammed ni, Ọlọrun lo n gbeni depo kii ṣe agbara tabi ipa teeyan ba ni, ẹni to ba wọle ibo,Ọlọrun ti kọ ọ ni tori ko sẹni to gbọn tayọ agbara rẹ.
O tun gba awọn tiwọn n japa mọnu lẹyin ibo nimọran pe ki wọn maṣe fina sori orule sun lọjọ iwaju, ẹni to fi laasigbo inu ẹgbẹ oṣelu rẹ silẹ lai yanju to lọọ koju ibo aarẹ gbọdọ kọgbọn bakan naa ni ẹni to gbojule awọn ọrọ ẹtan ori ayelujara gbọdọ ti mọ bayii pe, ibo ojukoju kii ṣẹgbẹ ibo ayelujara ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, o ni ọkọ ti wọn n ṣẹwọsi ti lọ
Comments
Post a Comment