Àṣíírí ìwòsàn fún ọkùnrin tí ẹpọ̀n rẹ̀ bá wú
Ko si awitunwi asan, a ti mọ iṣẹ ti ataalẹ maa n ṣe bakan naa ni a tun ti ka nipa iwulo oyin ṣugbọn nnkan taa fẹ mẹnuba ni lilo mejeeji papọ. Ohun kan to daju ni pe, ibaṣepọ to dan mọran wa laarin ataalẹ ati oyin leyi to ni anfaani iwosan rẹpẹtẹ ninu. Apapọ awọn eroja iwosan mejeeji yii maa n ṣe atọkun iwosan fun aisan iseemi, isetọ,otutu,ọfinkin ati ikọ. Ọkọọkan ninu awọn eroja wọnyii lo kun fọfọ fun iwosan pipe, ẹyin naa ẹ ro bi iwosan rẹ yoo ti kun to bi a ba pa mejeeji pọ.
Agbeyẹwo agbara iwosan ti apapọ eroja mejeeji le fun ọ niwọnyii:
O wulo gẹgẹ bi oogun adatọ paapaa julọ bi aya ba n rin eeyan, O dara fun ikọ,otutu ati ọfinkin. ataalẹ ati oyin papọ ma n ṣe afọmọ ọna ọfun paapaa julọ bi imu ba di gaga ti atẹgun ko rọna gba jade, rin ataalẹ diẹ ki o bu omi ọsan wẹwẹ sii pẹlu omi diẹ, gbe kana lori ina bi o ba ti gbọna daadaa, ẹ sọ ki ẹ bu oyin diẹ sii. Ẹ gbe e mu ni gbigbona bẹẹ.O dara ki eeyan to ba fẹẹ din ọra ara ku maa se ataalẹ mu ni gbigbona pẹlu oyin laarọ kutukutu
O maa n ṣiṣẹ gẹgẹ bi atura: Iwadii ti fidi ẹ mulẹ pe apapọ eroja mejeeji yii ma n ṣiṣẹ atura iyẹn ni pe o kapa ara riro, O n ṣe awotan iwosan fun aisan ọfun ati ṣiṣe afọmọ idọti to ba wa ninu kaa imu.
O dara fun iwosan ọkan: Laarọ kutu, se ataalẹ ni gbigbona ki o bu oyin sii, yatọsipe kii jẹ ki ẹjẹ di, o maa ko ọra ti ara ko ba nilo kuro bẹẹni ọkan yoo ma ṣiṣẹ daadaa nigbati ko ba si idiwọ koda o maa lo doju ija kọ gbogbo jankariwọ to ba wa lojuna ọpa to n gbe ẹjẹ kiri iṣan ara.
Ẹni to ba fẹẹ ni ookun ninu daadaa ki o gbiyanju lati se ataalẹ pẹlu ọsan lẹmọ ki ẹ wa bu oyin sii, eroja mẹtẹẹta yii ti to ẹ lati ṣẹgun aisan nitori kii jẹ ki kokoro aifojuri to le fa arunkarun duro laagọ ara.
O wulo gẹgẹ bi eroja fun iwosan inu kikun, iṣẹ nla ni iṣẹ gbalegbata ti apapọ ataalẹ ati oyin n ṣe lati ṣe afọmọ inu kikun tabi bi ounjẹ ko ba tete da lara, ki ara le ni alaafia, ẹ gbiyanju lati maa se ataalẹ mu ki ẹ fi oyin diẹ si i.
Apapọ oyin pẹlu ataalẹ dara fun jẹdijẹdi, o le dena aisan jẹjẹrẹ paapaa julọ bi a ba se e mu laarọ kutu ki a fi tẹlẹ ikun.
O maa n ṣiṣẹ tako awọn kokoro aifojuri to le ṣakoba fun ilera ara. bi o ba rẹ ataalẹ ati alubọsa ayu sinu oyin, ki o fi silẹ fun ọsẹ meji ko ti tọro daadaa ki o to maa fi ṣibi lo o, aṣiiri iwosan to wa nibẹ ko ṣe e fẹnu royin, ẹ maa fun awọn ọmọde naa mu, o dajupe ẹo nii paara ileewosan mọ. O maa n ṣafọmọ, ẹdọ, fuku,kidinrin bẹẹ ni ko nii jẹ ki aisan duro sini lara.
Ọkunrin ti ẹpọn rẹ ba wu, ki o lọọ ge ataalẹ ati ayu si wẹwẹ, rẹ sinu oyin fun ọsẹ meji gbako, maa mu ṣibi mẹrin mẹrin laarọ ati ni alẹ
Ẹni ti ko ba sanra ko gbọdọ dara de e ni mimu ṣugbọn o wulo lati fọ idọti ara kuro fun gbogbo eeyan, nitori naa, o kere tan a le ma se e mu ni ẹẹkan lọsẹ ṣugbọn ẹni to ba fẹẹ fọ ọra ara kuro le maa mu lojoojumọ tabi ẹẹmẹta lọsẹ
Alaboyun tabi ẹni to ba n tọju aisan ọkan lọwọ gbọdọ fọrọ lọ dokita rẹ ko to bẹrẹ sii lo ataalẹ o. Aṣiiri ibẹ ree, oogun ti yoo ṣiṣẹ iwosan pipe, owo rẹ kii pọ.
Comments
Post a Comment