Sanwó-Olú fẹ̀yìn àwọn alátakò rẹ̀ janlẹ̀

 

Ọlaide Gold

Oludije dupo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu  All Progressives Congress, Babajide Sanwo-Olu fẹyin awọn alatako rẹ, Abdulazeez Adediran oludije ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party ati Gbadebọ Rhodes-Vivour ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party janlẹ ninu idibo gomina ati ileegbimọ aṣofin ipinlẹ eyi to waye lọjọ Satide ni wọọdu kẹfa, ninu ọgba ileewe alakọọbẹrẹ St Stephen Primary school, Ẹiyẹkọle,lojuna Adeniji Adele nisalẹ Eko.

Abajade esi ibo wọọdu naa kede Sanwo-Olu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo ookanlelọgọfa nigbati Abdulazeez  Adediran  ni ibo meji ti Rhodes-Vivour ni ibo kan pere.

Ni nnkan bii aago meje aarọ lawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ti wa nikalẹ nigbati ibo bẹrẹ pẹrẹu ni deede aago mẹsan owurọ ti gbogbo ẹ si lọ ni irọwọrọsẹ.

Ni kete ti Sanwo-Olu dibo tan lo ba awọn oniroyin sọrọ bakan naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ara agbegbe naa ti wọn jade lati dibo nitoripe wọn n fẹ itẹsiwaju rere ‘Inu mi dun bi mo ṣe ri ẹyin eeyan tẹẹ jade lati ṣe ojuṣe yin gẹgẹ bi olugbe ipinlẹ Eko, mo fẹ mu da yin loju pe iṣẹ rere taa ti bẹrẹ yoo tẹ siwaju sii’.Awọn to kọwọọrin pẹlu gomina Sanwo-Olu wa sibudo idibo naa ni, iyawo rẹ abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu,ajafẹtọọ ọmọniyan,Joe Odumakin atawọn mi-in.

Ẹwẹ,gomina naa ko ṣai kan saara si ajọ eleto idibo fun bi ilana ti wọn tọ lasiko idibo gomina ṣe gbewọn si i ju ti atẹyinwa lọ.

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.