Ọ̀nà àbáyọ fún ọkùnrin tí àtọ̀ rẹ̀ lẹ tàbí ṣàn
Awọn nnkan tawọn eeyan ko fojusi nitoripe wọn kere niye lo maa n ṣiṣẹ iwosan nla, Ọlọrun ọba ti kuku da awọn kinni wọnyii sawujọ wa ṣugbọn ainimọ lo mu ọpọlọpọ rin irin Ibadan laarin Ọyọọ. Njẹ ẹyin tiẹ le ronu lọ sibi ofio bi o ṣe kere niye to. Ofio(Tiger nut) jẹ mọlẹbi agbọn, o da bi okuta wẹẹrẹ ṣugbọn o dun ni jijẹ. Bi awọn eeyan ba mọ agbara ti sodo sinu ofio ni, ṣe lo yẹ ki wọn maa fun awọn ọmọde jẹ latigba ewe nitori pe kii wu ọmọ miiran lati jẹ bi wọn ba dagba. Bi agbalagba paapaa ba fẹẹ bọ lọwọ aisan ọkan, jẹjẹrẹ,rọparọsẹ atawọn aisan miiran o yẹ ki o yan ofio laayo koda bi ounjẹ ba sun si eeyan ninu, bi iru ẹni bẹẹ ba jẹ ofio yoo ṣe igbọnṣẹ wọọrọwọ pẹlu irọrun.
Ẹ jẹ ka gbe iṣẹ iwosan ti ofio le ṣe yẹ wo
Oriṣii mẹta ni ofio, mẹtẹẹta naa ni eroja afaralookun kun inu rẹ fọfọ, o ni eroja to maa n fọ idọti kuro lara paapaa julọ awọn eefin to le ṣakoba fun ẹya ara, afẹfẹ ni eefin bẹẹ maa n ba wọle, o le jẹ eefin mọto tabi eyi to ba ẹnu wọle nipasẹ awọn ounjẹ sisun ta a maa n jẹ. Lọrọ kan ṣa, ofio kun fun oriṣiiriṣii fitamini afaralookun to wulo fun ilera.
Bi eeyan ba ṣẹṣẹ jẹun tan to wa jẹ ofio le e, onitọhun ti ṣẹgun inu kikun koda ko nii nira lati ṣe igbọnṣẹ . awọn eroja kan wa ninu rẹ to maa n ṣiṣẹ tako awọn kokoro aifojuri to le ṣe akoba fun ilera.
Awọn eroja afaralookun inu rẹ dara fun awọn to ni aisan itọ ṣuga, o maa n ṣe aato iwọn ṣuga lara. Ofio maa n ṣe afọmọ ọkan, ko si aaye fun kokoro jẹjẹrẹ bi eeyan ba n jẹ ẹ daadaa. Ororo to wa ninu ofio maa n fun ọkan lookun to nilo, eyi dara lati tako awọn aisan bii rọparọsẹ, aisan ọkan koda o le gbani lọwọ iku ojiji. Ororo to wa ninu ofio maa n je ki ẹjẹ ṣan geerege lara iyẹn ni pe ko fi aaye sile fun ẹjẹ didi.
Ofio maa n ṣiṣẹ gẹgẹ bi awogba arunkarun yala aisan ibalopọ, eyi teeyan ko lati ile igbọnsẹ tabi kokoro aifojuri teeyan ko lati inu afẹfẹ. Ọkunrin ti atọ rẹ ba lẹ gbọdọ maa jẹ eso yii daadaa, koda obinrin to ba n woju Ọlọrun fun ọmọ naa gbọdọ yan an laayo.
Ko saaye asọdun, ofio maa n ṣiṣẹ amarale fun ọkunrin ati obinrin bi eeyan ba n jẹ daadaa. O maa n ṣe ipalẹmọ inu ile ọmọ obinrin lati gba ọmọ duro. Eroja amaradide to kun inu rẹ fọfọ wulo fun takọtako ati awọn ti wọn ṣi fẹẹ ṣowo ọmọ bibi. Ko ni odiwọn, bi eeyan ba ṣe le jẹ ẹ si ni koda bi ẹ ba fẹ ko ṣiṣẹ daadaa ẹ lọọ mọ agbọn, ẹ fi asẹ sẹ ọmi rẹ lati yọ idọti kuro, ki ẹ maa mu u le ounjẹ lojumọ, ilera inu rẹ pọ ju owo rẹ lọ.
Comments
Post a Comment