Ó ti hàn gbangba báyìí pé Yorùbá ló l’Èkó-Adésopé

Ọlaide Gold

Aarẹ ẹgbẹ Oodua People’s Congress Reformed,Oloye Dare Adesope ti ranṣẹ oriire si gomina Babajide Sanwo-Olu fun bo ṣe jawe olubori ninu ibo gomina to waye lọjọ Satide,ọjọ kejidinlogun oṣu yii.  Adesope ṣalaye ọrọ naa gẹgẹ bi ogun ajaye lati bori awọn ajeji godogbo ti wọn fẹẹ maa pitan fun ọmọ onilẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ ‘Asiko yii lo yẹ ki iran Yoruba patapata tun ara wọn mu nitoripe igbesẹ tawọn ọmọ ilẹ Ibo gbe ninu idibo aarẹ ati ti gomina ti fi wọn han gẹgẹ bi ọta to yẹ ki gbogbo ọmọ ilẹ kaarọ oojiire tete mojuto ki alabọrun ma lọ dẹwu mọ wọn lọwọ’.

Ni itẹsiwaju alaye rẹ lo ti ṣapajuwe iwa imọ tara ẹni nikan tawọn ọmọ ilẹ ibo fihan ninu idibo to kọja, O ni, ṣaaju ki oludijẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ Labour Party, Peter Obi to darapọ mọ ẹgbẹ naa, ṣe ni ẹgbẹ ọhun tanka gbogbo ilẹẹwa to si faaye gba gbogbo ẹya ṣugbọn ni kete ti Obi gba asia ẹgbẹ naa lati dije dupo gẹgẹ bi aarẹ lo ti sọ ọ di ẹgbẹ ibo to bẹrẹ sii ṣe ẹlẹyamẹya. ‘Bi a ba foju inu wo o daadaa, gbogbo awọn oludije ti ẹgbẹ Labour fa kalẹ lati dupo sileegbimọ aṣofin nilẹ Yoruba ni ida ọgọrin wọn jẹ ẹya Ibo nigba ti kii ṣe pe awọn ọmọ Yoruba ko si ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party’.

Ọga agba ẹgbẹ OPC naa ni, apẹẹrẹ ti ẹ maa fi mọ pe awọn ọmọ ilẹ Ibo wa nibikan ni ti bi wọn ṣe ma n fẹ gaba lori awọn eeyan ti wọn ba nibẹ,apẹẹrẹ naa ni wọn fihan nipinlẹ Eko ṣugbọn tawọn ọmọ Yoruba jẹwọ ọmọ ọkọ fun wọn nitori naa ṣeni ki gbogbo ọmọluabi ronu ki wọn maṣe gbe ounjẹ alẹ wọn fun ologbo jẹ’.

‘Awọn gomina ilẹ Yoruba paapaa naa ni tiwọn lọwọ, wọn ti faaye gba awọn atọhunrinwa ju ninu iṣẹjọba wọn eyi ti ko ri bẹẹ lapa ọdọ tiwọn lọhun un,ṣeni ki wọn fun ọmọ Yoruba laaye lati jeeyan lori ilẹ baba wọn ki wọn si tete da awọn ajeji godogbo lọwọ kọ’.

Lakotan, Adesope ni ki ijọba mu aye rọrun fawọn eeyan ki wọn ye gbe owo gọbọi le ṣọọbu ti wọn kọ kawọn obinrin ilẹ Yoruba le ṣowo pẹlu irọrun. Bakan naa lo ranṣẹ ikinni ku oriire si Gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde,Dapọ Abiọdun atawọn ti wọn jawe olubori ninu idibo ileegbimọ aṣofin ipinlẹ. O wa ran wọn leti bawọn ọdọ ṣe fibo sọrọ lasiko idibo aarẹ eyi to jasi pe oloṣelu ti ko ba ṣe daadaa,awọn ọdọ yoo fọna ita han an.


Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.