Wolii Genesis ni kawọn ọmọ ijọ ṣi da sisan owo idamẹwaa atọrẹ duro
Ara tuntun leyi lawujọ awọn ojiṣẹ Oluwa, Wolii ijọ Genesis Global iyen Wolii Isreal Ọladele Ogundipẹ ṣe lọwọlọwọ bayii.
Ohun aṣeyatọ tẹni ami ororo Ọlọrun naa ṣe ni bo ṣe paṣẹ pe kawọn ọmọọjọ ṣi da owo idamẹwaa atowo ọrẹ duro na.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa gbe igbesẹ yii atari iṣoro tawọn eeyan n koju lọwọlọwọ lorileede yii.
Ipinnu yii waye lasiko to n waasu, o ni bi ara ba ti rọ awọn eeyan daadaa ti ko si ọwọngogo epo bẹntiro ati aisowo nigbooro mọ ni ki wọn to maa da owo silẹ Ọlọrun.
Ogundipẹ sọ pe" Ile aabo ni ṣọọṣi jẹ fun gbogbo eeyan nitori naa bi wọn ba n la iṣoro kan kọja, itura ni ijọ Ọlọrun gbọdọ wa fawọn eniyani rẹ, ko yẹ ki wọn da kun un.
Lakotan, wolii naa sọ pe yoo dara kawọn ojiṣẹi Ọlọrun mi in ṣe bẹẹ gẹgẹ nitoripe ara n ni awọn eeyan.
Comments
Post a Comment