Nigbati Tinubu ri ero rẹpẹtẹ to duro de e l'Eko, lo ba fijo bẹ
Ọlaid Gold
Ẹsẹ ko gbero ni papa iṣere Teslim Balogun to wa ni Surulere nipinlẹ Eko nibiti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti ṣe aṣekagba ipolongo ibo lati ṣatilẹyin fun oludije dupo aarẹ Orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa iyẹn Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
Orin oriṣiiriṣii lo n bọ lẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu yii gẹgẹ bii moriya leyi to mu ki gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa bẹrẹ sii fẹsẹ rajo ni kete to wọle sinu ọgba papa iṣere ọhun.
Awọn laamilaaka oṣere ori itage ilẹẹwa bẹrẹ latori Ọmọọba Jide Kosọkọ, Shaeed Balogun, Fathia Balogun, Rẹmi Oshodi Mama Surutu, Yinka Quadri,Folukẹ Daramọla,adẹrinpoṣonu Gbenga Adeyinka atawọn olorin mi-in ni wọn da awọn eeyan laraya.

LÁGBO ÒṢÈLÚ
Comments
Post a Comment