Mo fẹ́ẹ dàbí Jesu sọ Pásítọ̀ dèrò ọ̀run, kò tì í gbààwẹ̀ ogójì ọjọ́ àti ogójì òru tan tifun ẹ fi lẹpọ


Ọlaide Gold

Bawọn eeyan ṣe gbọ iru iku to Pasitọ kan, Francisco Barajah, lorileede Mozambique, ni wọn bẹrẹ sii fepe sin in lọ sajule ọrun koda awọn kan tọ ilẹ la wọn ni ko nii ba Ọlọrun nile. Nnkan ti alaimọkan ara rẹ gbiyanju wo ni aawẹ ogoji ọsan ati ogoji oru to si ti sọ fawọn ọmọ ijọ ẹ pe, Jesu yoo padabọ latara oun lẹyin ti aawẹ naa ba pari ṣugbọn ṣe loun funra ẹ pada lọọ ba Jesu.

Gẹgẹ bi alaye tawọn eeyan ṣe, wọn ni ọkunrin naa ko jẹ bẹẹni ko  fi omi kan ẹnu titi tawọn ẹya ara ẹ kan fi daṣẹsilẹ. Ohun tawọn onimọ iṣegun sọ ni pe, ifun nilo omi lati maa yi pada loorekoore, wọn lo ni iyẹ ọjọ ti ẹya ara naa le farada ọwọngogo omi mọ nitori naa bi ifun ba fẹẹ yi pada ti ko si ri omi, yoo bẹrẹ sii lọ pọ bẹẹni ọna yoo di mọ afẹfẹ tawọn ẹya ara yooku nilo lati ṣiṣẹ titi tẹni naa yoo fi gba sọda si aye mi-in.

Ọkunrin naa ti rọju gbaawẹ naa daaye kan koda awọn ọmọ ijọ rẹ ti n ṣajọyọ pe o ti n mu kinni ọhun jẹ, nnkan ti n ṣe e laagọ ara ṣugbọn o n rọju. Ọjọ kẹẹẹdọgbọn to ti n gbaawẹ naa ni nnkan ti yiwọ ṣugbọn ọjọ kejidinlogoji to ku gẹngẹ ko ba Jesu dọgba ni kinni naa burẹkẹ si i gẹgẹ bawọn aladugbo rẹ ti ṣalaye. Ọkunrin naa ti ru keegun, ko jẹ, ko mu bẹẹni ko wẹ koda ko le da dide nilẹ mọ ayafi bi wọn ba gbe e.

Nigba tawọn ara ile rẹ rii pe kinni naa ti yiwọ niwọn ba gbe e lọ sileewosan, awọn dokita gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, wọn gbiyanju lati fa omi si i lara ṣugbọn awọn ẹya ara rẹ ti kọṣẹ, wọn sa ipa wọn  ṣugbọn o pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

ÌRÒYÌN KÀYÉÉFÌ

Comments

Popular posts from this blog

Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun

Wàhálà nlá nijọ sẹ̀lẹ́!Nítorí tùràrí wọ́n lu wòlíì lálùbami,làwọn aláṣẹ bá gbe ṣọ́ọ̀ṣì tìpa

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.