Micheal to yinbọn mọ ọrẹkunrin aburo ẹ ti wa lahamọ ọlọpaa
Ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan,Micheal Ogundele tiwa lahamọ ọlọpaa bayii nibi to ti n jẹjọ ẹsun ipaniyan latari bo ṣe yinbọn mọ ọmọkunrin,Tobi Olubisi niluu Idi-Iroko nipinlẹ Ogun.
Micheal ni, oun ṣedajọ ọwọ fọmọkunrin naa toripe ko gbọ ikilọ. O ni, lọpọ igba loun ti sọ fun pe ko dẹhin lẹyin aburo oun ṣugbọn ko gbọ, lo ba sọ ara rẹ di ọdẹ to yinbọn mọ ẹtu.
O ti wa lahamọ ọlọpaa bayii nigbati ọmọkunrin to yinbọn mọ n gba itọju lọwọ nileewosan
Ìwà ọ̀dàràn
Comments
Post a Comment