Àwọn ọmọ bíbí ìlú Òró bu ọlá fún ọba wọn tuntun
Ọlaide Gold Wamuwamu ni gbọngan NUT Pavilion Events Centre nilu Ikẹja nipinlẹ Eko kun lọjọ Satide to kọja, awọn ọmọ bibi ilu Oro nipinlẹ Kwara tiwọn fi ilu Eko ṣebugbe ni wọn lọ pade Ọba Ọlaniyi Ọyatoye,Titiloye Olufayọ keji, iyẹn Oloro tilu Oro to ṣẹṣẹ gun ori itẹ awọn baba nla rẹ. Ọba Ọlaniyi Ọyatoye ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ awọn ọmọ bibi ilu Oro ti wọn wa nibẹ lọjọ naa, kabiyesi wure aṣeyọri lẹnu iṣẹ ti ẹni kọọkan n ṣe, Oloro tuntun naa ni, ogunlọgọ eeyan ni wọn mọ ilu Oro pẹlu ipede ‘Owo ni e jẹ’ tori naa, owo ko ni i wọn lapo ẹnikọọkan atawọn afẹnifẹre wọn. Siwaju si i, kabiyesi ṣeleri itẹsiwaju rere nilu Oro lasiko tiẹ, ọba alaye naa ni, gbogbo ẹbẹ awọn ọmọ oniluu loun ti gbọ bẹẹni igbesẹ lati fidi irẹpọ mulẹ ti n lọ labẹnu atipe didun lọsan yoo so laipẹ. Bo tiẹ jẹ pe, wọn ni oye ọba naa di fa-n-fa laarin awọn ọmọ oye bii meloo kan, ko to bọ sọwọ idile Titiloye Olufayọ, tijọba ipinlẹ Kwara si ti gbọpa aṣe le e lọwọ gẹgẹ bi Alayeluwa Oloro ti...
Comments
Post a Comment